AWỌN AFURASI ADIGUNJALE MEJI ATI ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN MẸWAA WỌ GAU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, January 4, 2021

AWỌN AFURASI ADIGUNJALE MEJI ATI ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN MẸWAA WỌ GAU L'EKOO


Ruth Akanni:

Ko din ni mẹwaa l'awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun t'ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko tẹ laipẹ yii lẹyin aṣẹ ti kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu pa wi pe oun ko fẹ iwa ọdaran kankan mọ nípinlẹ naa.
 
Hussein Hudu ati Ibrahim Bello pẹlu awọn mẹjọ kan lọwọ tẹ lasiko ti wọn n digun gba ọkada.
 
Awọn yooku ni Kabiru Tajudeen, Ibrahim Hamed, Elijah Ogbonna, Daniel Emmanuel, Chukwuma Abiaza, Rafiu Kolawole, Ibrahim Ogundimu, ati Nwerrih Elvis.
 
Yatọ si awọn wọnyii, Adegbenga Balogun ati Temitope Yusuf lọwọ tun tẹ pẹlu ibọn lagbegbe Eko Beach.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI