ẸGBẸ ỌDỌ ILẸ YORUBA ṢE IKILỌ NLA F’AWỌN FULANI DARANDARAN AT'AWỌN ỌDỌ IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 28, 2021

ẸGBẸ ỌDỌ ILẸ YORUBA ṢE IKILỌ NLA F’AWỌN FULANI DARANDARAN AT'AWỌN ỌDỌ IPINLẸ OGUN


Ẹgbẹ ọdọ ilẹ Yoruba, iyẹn Yoruba Youth Forum (YYF), ẹka ti ipinlẹ Ogun ti ṣe ikilọ fun gbogbo awọn Fulani darandaran patapata kaakiri orilẹ-ede yii, paapaajulo n'ipinlẹ Ogun lati tete pe awọn kọlọrọsi ẹda to wa laarin wọn lati jawọ ninu iwa buruku ko to o pẹ ju.

Bakan naa lo tun ṣe ikilọ f'awọn ọdọ ipinlẹ Ogun lati ri i pe wọn n gba ẹya mi in laaye laaarin wọn, ki wọn ma si ri gbogbo awọn ẹya ti ki i ṣe Yoruba gẹgẹ bi ọdaran.

Adari ẹgbẹ naa n’ipinlẹ Ogun, Kọmureedi Oluṣọla Adewusi lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi ranṣẹ s’AWIKONKO, eyi ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Kọmureedi Adeṣẹsan Ajayi bu ọwọ lu, nibi to ti sọ di mimo pe awọn ko ni laju silẹ lati maa jẹ k’awọn Fulani darandaran maa p’awọn ọmọ Yoruba nipakupa.

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe b’awọn Fulani darandaran yii ṣe n ṣeku p’awọn eeyan lọna aitọ, ni wọn n ji awọn ọmọ Yoruba gbe lati gba owo, ti wọn si tun n fipa ba awọn iyawo oniyawo laṣepọ, bakan naa ni wọn tun n fi awọn maluu wọn jẹkọ awọn agbẹ ti wọn n jiṣẹ jiya lati da oko.

Ọrọ awọn Fulani darandaran yii lo ti di ohun t’awọn eeyan n mu sẹnu lasiko yii wi pe ki ijọba apapọ tete wa nnkan ṣe si i ko to di pe ọrọ naa da ogun abẹle sile.

Ninu atẹjade owun Kọmureedi Oluṣọla Adewusi, ẹni to tun jẹ Ajagungbade ilu Itori, ipinlẹ Ogun sọ pe awọn n fi asiko yi sọ fun gbogbo awọn Fulani darandaran ti wọn wa n’ipinlẹ Ogun lati tete pe awọn oniṣẹ ibi aarin wọn si akiyesi pe iwa buburu ọwọ wọn ko tẹ awọn ọmọ onilu lọrun mọ, ki wọn si dẹkun lati maa ji awọn eeyan gbe, ati lati maa fi maluu jẹko awọn agbẹ.

Ọkunrin naa ni iwa alaafia to n jọba n'ipinlẹ Ogun lo jẹ ki wọn ronu kan ipinle Ogun lati de si, eleyi lo si mu ki won maa gba awọn ẹya mi in laaye laaarin wọn titi di asiko yii, wipe ki wọn ma ṣi anfaani naa lo.

Ajagungbade ni awọn iwa ti ko ba ofin orilẹ-ede Naijiria mu t’awọn Fulani darandaran naa n hu nilẹ Yoruba ku diẹ kaato, ati pe o n ko awọn lominu, paapaa bi ijọba apapọ ko wa nnkan ṣe si i.

Adewusi ni ko sẹni to le fọwọ lalẹ fun iran Yoruba wipe ki won laju silẹ k'awon ajoji maa ṣeku pa wọn, lai le sọrọ tabi gbeja ara wọn, ṣugbọn ,o sope suuru t’awọn n ṣe ni ko jẹ ki wahala ṣẹlẹ lojiji.

O te siwaju pe ibanujẹ ati ẹdun ọkan nla lo maa n jẹ f’awọn n’igba ti iroyin ba njade pe Fulani darandaran ṣe awọn ọmọ Yoruba niṣekuṣe, ti wọn si n ji wọn gbe gba owo lori ilẹ baba wọn.

O ni asiko ree t’awọn yoo dẹkun lati maa kawọ gbera wo iwa buruku t’awọn Fulani darandaran nse niyi, to si ni gbogbo nnkan ti yoo ba gba lawọn yoo fun un lati ri i pe awọn dẹkun iwa buruku naa.

Adewusi l'awọn  ko ṣetan lati ba ẹnikẹni jijakadi tabi ja ogun, bi ko ṣe lati jokoo sọ asọyepọ ti yoo gba alaafia laaye laaarin ilu.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii l’awọn Fulani darandaran ṣa obinrin kan niṣakuṣa, to si jẹ pe ori lo ko o yọ lagbegbe Ijẹbu.

L’ọdun diẹ sẹyin l’awọn Fulani ṣeku pa Alagba Omifẹnwa nilu Ado-Odo Ọta, Omifẹnwa to jẹ baba ọkan lara awọn oniroyin n’ipinlẹ Ogun ni wọn ṣeku pa sinu oko ẹ lasiko ti wọn n fi ẹran jẹko baba naa.

Awọn iwa yii ati oriṣiriṣi mi in ni ẹgbẹ ọdọ ilẹ Yoruba, YYF sọ pe awọn ko le gba mọ, ayafi k’awọn gbeja ara wọn.

O ni ti wọn ba  ri i pe awon koni tele ofin ile yourba ati orile ede yi, ki wọn wa ilu mi in ti wọn yoo ti maa lọ fi maluu wọn jẹko, tori pe bi ikoko ko ba ri ibi pẹlẹbẹ jokoo si, ko ni le duro gba omi si, leyi to tumọ si pe bi alaafia ati ifokanbale ko ba si nile Yoruba won ko ni tedo si.

Komureedi Adesola ni ki awọn ọdọ ṣọra lati ma ṣe dabaru eto aabo alaafia to n jọba n’ipinlẹ Ogun labẹ isakoso ijoba Gomina Dapọ Abiọdun. O ni gbogbo eeyan lo mọ pe ipinlẹ Ogun jẹ okan lara ipinlẹ ti alaafia ti n jọba julọ lorilẹ-ede yii, nitori naa lo ṣe ni ki wọn maa fi ifẹ ba gbogbo eeyan lo.

Adewusi ni , o wa labẹ ofin orilẹ-ede yii pe gbogbo ọmọ Naijiria ni ẹtọ lati gbe ibi to ba wu wọn, ṣugbọn ofin ko faaye gba iwa ijinigbe, ifipabanilopọ ati iṣeni-niṣekuṣe.

O ni bi wọn ba kofiri awọn ẹya mi in ti wọn n huwa ti ko tọ, ki wọn tete fa wọn le awọn agbofinro lọwọ, ki wọn ma si ṣe idajọ lọwọ ara wọn lati ma ṣe tẹ ofin loju mọlẹ.

Lakotan, o gbe oṣuba f'awọn ileeṣẹ agbofinro patapata n'ipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe n gbogun ti iwa ọdaran ni gbogbo ọna, to si ni ki wọn ri i daju pe wọn ko kaare lori sise eleyi, tori pe alaafia araalu lo ṣe koko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI