GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ SUN AYẸYẸ ỌJỌ IBI RẸ SIWAJU NITORI WOLII ỌLADELE GENESIS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 8, 2021

GBAJUMỌ SỌRỌSỌRỌ SUN AYẸYẸ ỌJỌ IBI RẸ SIWAJU NITORI WOLII ỌLADELE GENESIS


Kayeefi lo n jẹ fun pupọ awọn eeyan lori bi gbajugbaja sọrọsọrọ nni to n mi igboro Naijiria titi lasiko yii, Kọlawọle Atanda Adejojo t'ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar ṣe sun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ siwaju bayii, nitori Wolii Ọladele Ogundipẹ t'ọpọ eeyan mọ si Genesis Global.

Ọjọ kọkanla oṣu yii, iyẹn ọjọ Tọside ọsẹ yii ni ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun marundinlaadọta (45) gbajumọ sọrọsọrọ naa, ṣugbọn to sọ pe ọjọ kẹwaa oṣu kẹta loun fẹẹ ṣe.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọjọ naa ni ayẹyẹ ọjọ ibi Wolii Ọladele Genesis, ṣugbọn ti ọkunrin yii sọrọsọrọ yii ti sọ pe ọjọ naa loun fẹẹ ṣe ọjọ ibi oun, ta a si gbọ pe ayẹyẹ nla ni wọn fẹẹ fi ṣe.

Pupọ awọn to gbọ ni wọn ti beere idi ti ọkunrin naa fi pinnu lati gbe igbesẹ yii, ṣugbọn ti Kasnaty ko ti i sọ idi pataki to fi gbe igbesẹ naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI