AARE ỌNA KAKANFO TU AṢIRI OGUN TO N JA ILẸ YORUBA, O L'AWỌN FULANI KỌ N'IṢORO YORUBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 21, 2021

AARE ỌNA KAKANFO TU AṢIRI OGUN TO N JA ILẸ YORUBA, O L'AWỌN FULANI KỌ N'IṢORO YORUBA


Ruth Akanni:

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Iba Gani Abiọdun Ige Adams ti sọ pe ki i ṣe awọn Fulani ni iṣoro to n d'ojukọ ilẹ Yoruba, bi ko ṣe pe awọn Yoruba gan an ni iṣoro ara wọn.
 
O ni iwa ọdalẹ to wa laaarin ẹya Yoruba lo n fa ipadasẹyin Yoruba, ti ko si jẹ ki wọn ni ilọsiwaju.
 
Iba Gani Adams lo sọrọ naa laipẹ yii nibi ipade awọn agba ilẹ Yoruba, eyi to waye nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ eto aabo ilẹ Yoruba, iyẹn l'Ọjọru ti i ṣe Wẹside to kọja yii. 
 
Iba Gani Adams sọ pe to ba ti di ọrọ nnkan to ni i ṣe pẹlu eto aabo ilẹ Yoruba, awọn Yoruba ti wọn jẹ ọdale ni ki wọn ba wi, ki i ṣe ẹya Fulani, to si ni kekere ni t’awọn Fulani ninu ọrọ to wa nilẹ yii. O ni bi Yoruba ba le fọwọsọpọ, ki wọn si wa ni iṣọkan, nnkan yoo maa lọ deede laaarin wọn. 
 
Aarẹ Ọna Kakanfo, to tun jẹ olori ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba, iyẹn Oodua People’s Congress, OPC siwaju si i lo tun bu ẹnu atẹ lu b’awọn Ọlọpaa ṣe foju awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ba ile ẹjọ lori bi wọn ṣe mu olori awọn Fulani darandaran ti wọn fẹsun buruku kan nilu Ibarapa, iyẹn Iskilu Wakili. 
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Bi a ko ba tete wa nnkan ṣe sọrọ eto aabo ilẹ Yoruba to mẹhẹ, o ṣeeṣe ki nnkan tu buru jai si i. A ni awọn agba Yoruba kan ti wọn ko wa s'ibi ipade yii, nitori ajakalẹ arun Covid-19 ti wọn fi kẹwọ, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Inu oṣu kẹta ọdun 2017 lati ṣe iru ipade bayii kẹyin nilu Ibadan. Latigba ti mo ti di Aarẹ Ọna Kakanfo, mo ti dide lati ja fitafita, ṣugbọn t'awọn eeyan ṣi n beere lọwọ mi pe ki ni mo n ṣe sọrọ eto aabo ilẹ Yoruba.
 
"A ni lati jokoo papọ, ka jọ fọwọsowọpọ gbaruku ti awọn gomina ilẹ Yoruba lori ọrọ eto aabo. Awọn gbajugbaja alẹnulọrọ nilẹ Yoruba ni wọn ti gbagbe orirun wọn.
 
"Fun awọn to n beere lọwọ mi pe igbesẹ wo ni mo n gbe lori eto aabo ilẹ Yoruba, mo fẹ fi ye wọn pe nigba ti mo lo ẹyọkan lara awọn agbara ti mo ni, gbogbo ilu lo mi titi fun ọsẹ meji pere. Awọn ọmọ wa lọ sinu igbo lati mu igbakeji Iskilu Wakili at'awọn mẹta ti wọn jọ n ṣiṣẹ, wọn si fa wọn le awọn ọlọpaa lọwọ.
 
"Lẹyin ẹ la tun tọpinpin gbogbo irin Wakili fun bi oṣu kan, ti a si pada rọwọ to ohun at'awọn mẹta nilu Ibarapa. Awọn to mu Wakili ni wọn tun ti mọle, ti wọn tun pada fi wọn silẹ. N'igba ti wọn f'oju ba ile ẹjọ l'ọjọ Mọnde, ẹsun apaayan didarapọ mọ ẹgbẹ buruku ni wọn fi kan wọn.
 
"Ibi to yẹ ki Yoruba ti ronu niyii. Igbesẹ ti n lọ lati kapa eto aabo ilẹ Yoruba. Awọn Fulani kọ ni iṣoro wa, bi ko ṣe awọn eeyan wa. Mo ni awọn aṣiri nipa awọn ọdalẹ laaarin wa. Ohunkohun to le wu ka ṣe, a ko ni i dojuti awọn gomina wa."
 
Bakan naa lo sọ pe oun ti ṣepade pọ pẹlu gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, to si loun nifẹẹ si igbesẹ t'awọn gomina ilẹ Yoruba n gbe lori ọrọ eto aabo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI