BABALAWO ATI BIRIKILA TO F'IYA AT'ỌMỌ Ṣ'OOGUN OWO TI HA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 21, 2021

BABALAWO ATI BIRIKILA TO F'IYA AT'ỌMỌ Ṣ'OOGUN OWO TI HA O

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ babalawo ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn kan, Baoku Gbuyi ati ọkan lara awọn onibara rẹ, Ọlamide Odulaja toun jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn lori ẹsun ipaniyan.
 
Iyale ile kan, Modupẹọla Fọlọrunṣọ atti ọmọ rẹ, ọmọ ọdun mẹrin, Peter Fọlọrunṣọ la gbọ pe Gbuyi ati Ọlamide fi ṣoogun owo ninu oṣu keji ọdun yii, iyẹn nilu Ijẹbu-Igbo.
 
Ọkọ Modupẹọla la gbọ pe o lọ sọ f'awọn ọlọpaa lọjọ kẹrinla oṣu keji wi pe oun ko ri iya ati ọmọ oun ti wọn jade nile lọjọ kẹtala oṣu keji, to si bẹ wọn pe ki wọn ba oun wa wọn.
 
AWIKONKO gbọ pe ọkunrin naa ti daamu titi lati ri iyawo ati ọmọ rẹ, ṣugbọn ti ko ri wọn. Wọn ni gbogbo idaamu rẹ lati ri wọn lo ja si pabo, ko to di pe o gba teṣan ọlọpaa lo lati fi to wọn leti.
 
Iwadii t'awọn ọlọpaa ṣe lo f'idi rẹ mulẹ pe awọn kan ri Ọlamide ati Gbuyi pẹlu obinrin naa ati ọmọ rẹ lọjọ ti d'awati. Eyi lo jẹ k'awọn ọlọpaa bẹrẹ si i wa Ọlamide kaakiri. Igba ti wọn yoo fi mọ, ilu Ibadan la gbọ pe wọn gburo Ọlamide si, ti wọn si lo o ti lowo gidi.
 
Loju ẹsẹ t'awọn ọlọpaa ri Ọlamide ni wọn ti gbe e, igba to de teṣan l'awọn ọlọpaa ṣẹṣẹ sọ ẹṣẹ rẹ fun un, to si jẹwọ pe loootọ ni, ati pe oun pẹlu babalawo to ba oun ṣiṣẹ naa l'awọn jọ ji Fọlọrunṣọ ati ọmọ rẹ gbe.
 
Ọlamide lo si mu wọn de ile Gnuyi, iyẹn babalawo rẹ to n gbe ladugbo Ararọmi, Japara nilu Ijebu Igbo. Igba ti wọn yoo fi debẹ, wọn l'awọn Irunmọlẹ ti sọ pe ko kuro nilu naa, to si ko ẹru lo n gbe labule Kajọla to wa nilu Awa Ijebu, nibẹ si l'awọn ọlọpaa ti lọ gbe e.

Gbuyi nigba n jẹwọ ẹṣẹ sọ pe ẹjọ oun kọ, tori pe Ọlamide lo wa ba oun fun oogun owo toun si sọ pe ko lọ wa ori oku wa, o n'igba ti ko tete ri ori oku l'awọn fi pinnu lati ji Fọlọrun ṣọ ati ọmọ rẹ gbe, t'awọn si fi wọn gun ọṣẹ owo.

Bẹẹ lo sọ pe awọn ti ju oku ọmọ naa sinu ṣalanga ki aṣiri ma ba a tu. O ni kani awọn mọ pe aṣiri maa pada tu ni, awọn ki ba ti ma ṣiṣẹ naa rara, k'awọn si maa duro de asiko Ọlọrun.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju lori awọn mejeeji ko to di pe wọn f'oju wọn ba ile ẹjọ, bẹẹ lo gb'awọn eeyan ti wọn n jiṣẹ-jiya lasiko yii lamọran wi pe ki wọn duro de asiko Ọlọrun to dara julọ lati ni owo, ati pe ki wọn kun fun adura rẹpẹtẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI