RUDURUDU N KAN ILẸKÙN NILE AGBARA NAIJIRIA, BUHARI GBỌDỌ GBADURA GIDI - WOLII AYODELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 21, 2021

RUDURUDU N KAN ILẸKÙN NILE AGBARA NAIJIRIA, BUHARI GBỌDỌ GBADURA GIDI - WOLII AYODELE


Ruth Akanni: 

Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, Primate Elijah Ayodele ti gba Aarẹ Muhammadu Buhari lamọran lati kun fun adura nla lati dẹkun rudurudu to ṣeéṣe ko ṣẹlẹ nilu Abuja.

Ninu ìjọsìn ọjọ isinmi oni ni Wolii Ayodele ti sọrọ naa, to si ni àwọn aṣiri nla kan yoo tu lati ilu Abuja kaakiri agbaye.

Nibẹ lo tun ti sọ pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC yoo koju awọn wahala kọọkan lọdun 2023, ti nnkan ko si ni i rọrun fun wọn.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Naijiria ko ni i lowo lọwọ, gbese wa maa lagbara si i, eyi yoo si ṣakoba fun APC lọdun 2023, mi o ri i pe nnkan yoo rọrun fun wọn ni 2023.

"Nnkan ti mo ri lagbara gan an, Naijiria ko ti i ri nnkankan bayii, eto ọrọ aje yoo bajẹ, eyi yoo si pa eto ọrọ aje awọn ile ifowopamọ at'awọn ijọba ipinlẹ lara.

"Awọn to n dari Naijiria ti ṣi orilẹ ede yii dari, wọn si ti ba eto ọrọ aje jẹ, awọn aṣiri kan yoo tu ni NNPC.

"Wọn tun ṣi maa kọlu ọkọ akọwọrin ijọba, Buhari nilo adura, mo ri rudurudu nla nile agbara, eyi to buru gidigidi ti yoo si tu awọn aṣiri si agbaye."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI