LẸYIN ỌGỌTA ỌDUN, ILU KUSUMODI YAN BAALẸ TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 21, 2021

LẸYIN ỌGỌTA ỌDUN, ILU KUSUMODI YAN BAALẸ TUNTUN


Ẹsẹ ko gbero nilu Kusumodi to wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi/Owode, ipinle Ogun lopin ọsẹ to kọjá yii nigba tàwọn ọmọ ati araalu naa lati yan Oloye Taiwo Elijah Alli-Balogun gẹgẹbi baalẹ tuntun funra wọn.

Ọgọta ọdún sẹyin ree ti wọn sọ pe ilu naa ti tuka lẹyin wahala kan tó ṣẹlẹ níbẹ, ti wọn si lawọn eeyan ko boju wo ẹyin wo mọ.

Wọn ni oṣu mẹjọ sẹyin ree ti Oloye Alli-Balogun, ẹni to tun jẹ gẹgẹ bi Luwoye ilu Ẹgba dide lati da ogo ilu naa to ti sọnu tipẹ pada.

Oṣù kẹfà ọdún to kọjá la gbọ pe Alake ile Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ bu ọwọ lu Oloye Alli-Balogun lati di baalẹ ilu naa.

Inu igbo kijikiji la gbọ pe ilu naa wa nigba t'awọn eeyan de'bẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ṣugbọn ni bayii, ilu Kusumodi ti di ilu nla laaarin oṣù mẹwàá pere.

Ọsẹ kan gbako la gbọ pe wọn fi ṣe ayẹyẹ iwuye ati ọdun Kusumodi to waye ninu gbọngan ilu naa lana an ti i se Satide, ìyẹn Abamẹta.

Alaga eto ayẹyẹ naa, Oloye Anthony Ọlayiwọla Oliyide lasiko to n sọ pe bi wọn ṣe yan Oloye Taiwo Alli-Balogun ko ṣẹyin Ifa to tọ wọn sọna.

Oloye Oliyide to je Oluwo ilu Igbore rọ gbogbo awọn ọmọ ilu naa jakejado agbaye lati pada wa sile wa a mu idagbasoke ba ilu wọn.


Baalẹ tuntun naa, Oloye Alli-Balogun ninu ọrọ tirẹ rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Ogun lati fun wọn ni omi, ina mọnamọna at'awọn nnkan amayedẹrun.

Yoruba bọ, wọn ni igi kan ko le da igbo ṣe lo jẹ ki baalẹ tuntun yii yan awọn oloye ti yoo ba a ṣiṣẹ, lara wọn si ni Oloye Ṣẹgun Ọladipupọ, Afọbaje; Oloye Arabinrin Ẹgbẹtokẹ, Iyalode; Oloye Abdul-Lateef Rabiu Sunday, Ọkanlọmọ; Oloye Sunday, Olori-Ọdọ ati Oloye Hammed Akanbi Adetunji toun je Majẹobajẹ.

Diẹ lara awọn fọto bi eto naa ṣe lọ:No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI