A mọ riri iṣẹ ti ẹ ṣe - SWAN gbe oṣuba kare f'ẹgbẹ elere idaraya Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 22, 2021

A mọ riri iṣẹ ti ẹ ṣe - SWAN gbe oṣuba kare f'ẹgbẹ elere idaraya Kwara


Ẹgbẹ akọroyin ere idaraya, iyen Sports Writers Association of Nigeria, SWAN, ẹka ti ipinlẹ Kwara ti gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn ikọ elere idaraya kaakiri ipinlẹ naa fun ipa ribiribi ti wọn ko l'asiko idije ati ifigagbaga to waye laipẹ yii n'ipinlẹ Edo, iyen National Sports Festival.
 
 
Akọwe ẹgbẹ SWAN n'ipinlẹ, Ọlayinka Owolẹwa naa atẹjade to gbe sita l'Ọjọ Iṣẹgun Tusidee ana lo ti sọ pe awọn aami ẹyẹ t'awọn eeyan naa gba fi han pe wọn mọ nnkan ti wọn lọ n'ibi idije naa, to si l'awọn dupẹ pe wọn ko ja wọn kulẹ.
 
 
Owolẹwa ni awọn akitiyan Gomina AbdulRazaq l'ori ọrọ eto idaraya ko ja s'ofo pẹlu bi wọn ṣe lọ tayọ kọja afẹnusọ nibi idije naa, ati pe iwuri nla lo jẹ fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa jakejado.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI