Àrokò ni iku Derby jẹ f'awọn Ààrẹ ilẹ̀ Áfríkà, púpọ wọn lo ṣi máa ku - Wòlíì Ayọdele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 22, 2021

Àrokò ni iku Derby jẹ f'awọn Ààrẹ ilẹ̀ Áfríkà, púpọ wọn lo ṣi máa ku - Wòlíì Ayọdele


Ọlaide Ọṣinuga, Lagos

Aláṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church to wa n'Ipinlẹ Eko, Primate Elijah Ayọdele ti sọ pé púpọ awọn Ààrẹ ilẹ̀ Áfríkà ni wọn ṣi máa dagbere f'aye lori iwa àìgbọràn wọn, eyi tó ní àrokò ni iku Ààrẹ ilẹ Chad, Idriss Derby jẹ fún gbogbo wọn.

Oṣù kan lẹyìn ikú Ààrẹ orílẹ-èdè Tanzania, John Magufuli ku ni iku Derby naa tun wọlé wẹrẹ.

Primate Ayọdele ninun atẹjade to gbe sita laipẹ yii lo ti sọ pé àyàfi bi gbogbo wọn ba le ronu piwada, ki wọn si kọ'ju si Ọlọrun lati maa ṣe atọna wọn ni ohun buruku ko ni maa ja lu ohun buruku fun wọn.
 
O tẹsiwaju pe ilẹ Afrika jẹ ilẹ kan ti Ọlọrun bukun julọ l'agbaye, ṣugbọn adari ilẹ Afrika ni wọn n fi oju tẹmbẹlu Ọlọrun, ti wọn ko si ba a ṣiṣẹ pọ, eyi to n fa ajalu iku awọn Aarẹ ilẹ Afrika.
 
Yatọ si eyi, o ni bo tilẹ jẹ pe awọn Aarẹ tẹlẹri l'awọn orilẹ-ede ilẹ Afrika ṣi maa ku, ṣugbọn ti ko ni i yọ awọn Aarẹ to n jẹ lọwọlọwọ silẹ, ayafi bi wọn ba gbe awọn igbesẹ to ba yẹ tabi ki wọn kọ iwe f'ipo silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI