Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti tu awọn aṣiri tẹnikẹni ko tí ì gbọ ri, pàápàá lori idi pataki ti ijọba rẹ ṣe n ni idagbasoke ati ilọsiwaju alailẹgbẹ.
Ana tí í ṣe ọjọ Isẹgun, ìyẹn Tusidee ni Gomina AbdulRazaq sọrọ yii jade nilu Abuja nibi ìfilọ́lẹ̀ iwe kan ti Sẹnetọ Ibrahim Yahya Oloriẹgbẹ kọ nipa ara rẹ.
Gomina AbdulRazaq sọ pé lára àwọn Sẹnetọ toun máa n gbe oṣuba kare fún ni Sẹnetọ Oloriẹgbẹ, tori to mọ pataki ijọba Otogẹ tàwọn n ṣe ni ipinlẹ Kwara.
O ni bi ko ba sí pé àwọn aṣòfin ipinlẹ naa, at'awọn aṣoju-ṣofin nilu Abuja to fi mọ awọn alẹnulọrọ nipinlẹ náà ti wọn n gbaruku ti ìṣàkóso oun ni, ijọba ko ba ma ti rọrùn foun lati ṣe.
Pàápàá jùlọ, o ni b'awọn ṣe fagile ọrọ baba isalẹ nìdí òṣèlú at'awọn nnkan mi in ni ipinlẹ naa tun jẹ ọkan gboogi lara idi tàwọn fi n ni ilọsiwaju rere.
Síwájú sí í lo sọ pé "Ijọba wa n jẹ anfààní ibaṣepọ to dan mọnran láàárín àwọn aṣojú-ṣofin nipinlẹ náà àti nilu Abuja. Eyi ló n jẹ ká máa rí ọwọ mu.
"A ti ri í daju pe ile igbimọ aṣofin kẹsán an bi awọn aṣofin ko ṣe ni alatako lati ṣiṣẹ wọn. Pelu bi Naijiria ṣe ni ipenija eto ọrọ ajé tó, a ṣí tun n ri ilọsiwaju rere, pàápàá lẹka ti reluwee, iṣẹ àgbẹ àti ikansira-ẹni.
"Awọn àṣeyọrí yìí kò sẹyìn ibaṣepọ to dan mọnran láàárín àwọn aṣojú-ṣofin at'awọn aṣofin orilẹ ede yii."
Lakotan, AbdulRazaq lórúkọ ijọba rẹ at'awọn ọmọ ipinlẹ Kwara, O dupẹ lọwọ Sẹnetọ Oloriẹgbẹ.
No comments:
Post a Comment