Ekiti ni wọn ti jí Ọba Oyewunmi gbe, ipinlẹ Kwara ni wọn ti pada ri i - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, April 21, 2021

Ekiti ni wọn ti jí Ọba Oyewunmi gbe, ipinlẹ Kwara ni wọn ti pada ri i


Bo tilẹ jẹ pé iyalẹnu lo n jẹ lori bi wọn ṣe láwọn fijilante ipinlẹ Kwara ṣe rí Ọba Oyewunmi, Ọbadu tilu Ilemọṣọ nipinlẹ Ekiti gba jade kuro lọwọ àwọn ajinigbe, ṣugbọn sibẹ, idunnu nla lo jẹ pé ẹmi Kabiyesi náà ko lọ sí i.

Ọsán ana ti í ṣe Tusidee la gbọ pé wọn ti Kabiyesi náà nibi tàwọn ajinigbe yii lọ júù sí nínú igbó kijikiji kan ti wọn lo wa l'agbegbe Obbo-Aiyegunlẹ, ipinlẹ Kwara.

Ọjọ mẹfa gbako ni Ọba Oyewunmi lo lahamọ awọn ajinigbe yii, ki wọn to o fi sílẹ.

Bó tilẹ jẹ pé a kò gbọ boya awọn ajinigbe naa gba owo ti wọn n béèrè fún ko to di pe wọn yọnda Kabiyesi náà láti máa lọ, ṣugbọn agbẹnusọ fawọn ọlọ́pàá ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu sọ pé Kabiyesi to wa nibi to ti n gba ìtọjú.

O ni ileeṣẹ ọlọ́pàá, ileeṣẹ fijilante ati ileeṣẹ Amọtẹkun ni wọn jọ pawọpọ lati lọ gba Kabiyesi náà sílẹ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI