ABDULRAZAQ YAN IGBIMỌ TUNTUN LATI ṢE IWADII TITA DUKIA IJỌBA DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 1, 2021

ABDULRAZAQ YAN IGBIMỌ TUNTUN LATI ṢE IWADII TITA DUKIA IJỌBA DANU

 
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti yan igbimọ ẹlẹni meje tuntun kan ti yoo ri si bi wọn ṣe ta awọn dukia ijọba lọna ti ko tọ, ati pe bi wọn ṣe awọn nnkan to jẹ t'ijọba ipinlẹ naa ko salọ, iyẹn laaarin ọdun 1999 si ọdun 2019.
 
Igbimọ naa ti wọn pe ni White Paper Committee la gbọ pe bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun-un ọdun 1999 si ọjọ kọkandinlọgbọn ọsu karun-un ọdun 2019, eyi to jẹ ogun ọdun gbako ni wọn yoo maa fi ṣe iwadii naa.
 
Lara awọn ọmọ igbimọ naa ti wọn tun jẹ ogbontarigi agbẹjọro, ni Amofin Husseini Buhari to jẹ alaga; Oṣiṣẹ fẹyinti Joel Oluṣọla Ọladipọ; Hajia Aisha Muhammed; Ọnọrebu Ọlabọde Towoju; Muri Adi; Funmilayọ Gold ati Mayaki Babadzuko Madu toun jẹ akọwe.
 
Yatọ si awọn wọnyii ti Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRazaq yan, o tun yan Ọgbẹni Ishiak Yakubu Sannu gẹgẹ bi alaga igbimọ iṣakoso ile-ẹkọ Kwara State College of Health Technology to wa nilu Ọffa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI