ABDULRAZAQ ṢABẸWO SI ỌJA ORO TO JONA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 13, 2021

ABDULRAZAQ ṢABẸWO SI ỌJA ORO TO JONA


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti ṣe abẹwo ibanikẹdun si gbajugbaja ọja aarin gbungbun Oro, ìyẹn Oro Central Market to wa nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ naa.

Ana ti i ṣe ọjọ Aje Mọnde yii ni ina deede ṣẹyọ lọja naa, nibi ti ọpọlọpọ ṣọọbu ti jona kọja afẹnusọ.

AWIKONKO gbọ pe awọn idọti ti wọn n da si ẹyin ọja naa, eyi tàwọn èèyàn dana sun lo mú ọkan lara awọn ṣọọbu to wa nitosi, to si da wahala nla silẹ.

Gomina AbdulRazaq nigba to n sọrọ nibi abẹwo naa lonii gi aidunnu rẹ han, to si ṣeleri pe ijọba yoo wa nnkan ṣe lati ran awọn to padanu dukia ati ọja wọn lọwọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI