Akitiyan wa lori ere idaraya n so eso rere - Gómìnà AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 18, 2021

Akitiyan wa lori ere idaraya n so eso rere - Gómìnà AbdulRazaq


Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ pe inu oun n dun pe gbogbo akitiyan wọn lẹka eto ere idaraya n'ipinlẹ naa n so eso rere, to si ni aridaju rẹ wa lati inu idije ilẹ yii to ṣẹṣẹ pari n'ipinlẹ Edo.

Ọsẹ to kọja yii ni idije ati ifigagbaga idaraya ilẹ Nàìjíríà, ìyẹn National Sports Festival waye nipinlẹ Edo, ti awọn ipinlẹ mẹjọ ọtọọtọ si sun soke lori tábìlì.

AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ sọ pe ìpinnu awọn lati ji ẹka ere idaraya n'ipinlẹ naa dide láwọn ti ri ipa rere to ti n ṣẹlẹ n'ipinlẹ Edo lọsẹ to kọja yii, pẹlu bo ṣe ni aami ẹyẹ ti ko din ni mẹẹdogun láwọn gba wa sílé.

Olùdámọ̀ràn pataki fun Gómìnà AbdulRazaq lori ọrọ ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ, Attahiru Ibrahim to gba ẹnu ọgá rẹ sọrọ sọ pe Goolu (Gold) meje, Aami ẹyẹ alawọ eeru (Silver) mẹfa, ati aami ẹyẹ koriya (Medals) mọkanlelọgbọ̀n, ti gbogbo rẹ sì jẹ mẹrinlelogoji láwọn gba wa sílé, eyi to lo jẹ iwuri nla.

O tẹsiwaju ninu idije yii to wa nilu Abuja lọdun 2018, ipo kẹtalelogun ni Kwara wa lori tabili, to si ni apapọ aami ẹyẹ ti wọn gba wa sílé jẹ mejila pere.

O ni àpẹẹrẹ rere ni tọdun yii jẹ wi pe akitiyan wọn ko ja si asan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI