Mi o ki i ṣe ẹlẹ́dẹ̀ igàn, emi ko le gba abẹrẹ Korona láyéláyé - Biṣọọbu Oyedepo pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 18, 2021

Mi o ki i ṣe ẹlẹ́dẹ̀ igàn, emi ko le gba abẹrẹ Korona láyéláyé - Biṣọọbu Oyedepo pariwo sita


Olori ati Oludasilẹ ṣọọṣi Living Faith káàkiri àgbáyé, Biṣọọbu David Oyedepo ti sọ pe oun ko le gba abẹrẹ àjẹsára ti Korona nile aye oun, tori pe oun ki i ṣe ẹlẹ́dẹ̀ igàn (guinea pig).

Biṣọọbu Oyedepo lo sọrọ naa laipẹ yii ninu isin adura ti ìjọ rẹ, eyi ti wọn pe ni Covenant Hour of Prayer programme.

Nibẹ ni Biṣọọbu Oyedepo sọ pe gbogbo àgbáyé kan n ta ara wọn jẹ lasan ni, tori pe ijọ naa ni idahun si gbogbo ìṣòro tí wọn n wa kiri.

O sọ siwaju ninu ọrọ rẹ pe "Emi ko ti i ri iran ti ẹ ti ma máa pọn ọn ni dandan f'awọn eeyan lati gba abẹrẹ àjẹsára Korona, ko ba iwa ọmọluwabi mu; ko t'ọna rara. Mi o ki i ṣe agbẹjọro, ṣugbọn mi o ro pe o ba ofin mu.

"Ẹ ko le wa si ile mi lati sọ pe ẹ fẹẹ fun mi ni abẹrẹ. Lori kinni? Ṣe mo fi iwe pe yin ni? Ọrọ ara wọn ko ye wọn. Ṣugbọn ìjọ ni idahun. Ṣe ẹyin ri i ki arun naa de ibi? Bawo lo ṣe fẹẹ wọ ẹnu geeti? Ṣe afẹfẹ lo fẹẹ gba wọlé ni? Abi bawo?

"Obinrin kan ṣẹṣẹ wo lulẹ lẹyìn to gba abẹrẹ naa tan n'ipinlẹ Kaduna ni. Iru aye wo ree? Ṣe awọn eniyan ti wa a di ẹlẹdẹ igan ni? Rudurudu ti ba aye, sibẹ ìjọ n bori.

"Fun idi eyi, bi ìjọ ṣe n bori yóò jẹ ki ìgbéraga aye máa tẹriba. Wọn ko mọ ohun ti wọn le ṣe mo. Ni ìkẹyìn ọjọ, ìjọ yoo maa jọba lori agbara ati ògo. Ileri ati ipinnu Ọlọrun nìyẹn.

"Ko si ẹbẹ kankan. Awọn ẹyẹ nla kan wa nilẹ wa, ti wọn n sọ pe 'ẹ ma gba a, ẹlẹtan ni wọn'. Ẹ jẹ ki n ri ẹnikan ti yoo wa fun mi labẹrẹ naa.

"Ṣe ẹ fẹẹ so mi lọwọ mọlẹ ni? Bawo? Ṣe mo pe yin ni? Mo mọ pe ẹ ti dakẹ, ṣugbọn ẹ ṣi maa gbọ púpọ rẹ. Iṣẹ mi ni lati tu aṣiri èṣù ati awọn ọmọ ogun rẹ, ẹ wa ibi gba, awa ki i ṣe ẹlẹdẹ igàn."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI