Ẹ ma ṣe fi iṣẹ yín ṣeré o - TESCOM ṣe ìkìlọ nla f'awọn Tiṣa tuntun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, April 30, 2021

Ẹ ma ṣe fi iṣẹ yín ṣeré o - TESCOM ṣe ìkìlọ nla f'awọn Tiṣa tuntun


Alaga Ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn olukọ n'Ipinlẹ Kwara, ìyẹn Kwara State Teaching Service, Mall Bello Tahueed Abubakar ti ṣe ìkìlọ fún gbogbo àwọn olùkọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gba s'iṣẹ pé kí wọn má ṣe fi iṣẹ wọn ṣeré rárá.

AWIKONKO gbọ pé púpọ lára àwọn olùkọ, ìyẹn Tiṣa tuntun t'ijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ gba s'iṣẹ ti n lọ káàkiri láti máa bẹbẹ pé kí wọn má ṣe gbé wọn lọ sí ọnà tó jìnnà síbi tí wọn n gbe.

Wọn l'awọn eeyan naa n bẹbẹ pé kí wọn má ṣe gbé wọn lọ s'awọn igberiko bi abule to jẹ pé inú igbó ni wọn wà, ti wọn sì ni ojutaye, ìyẹn láàárín igboro láwọn n fẹ lati ṣiṣẹ olukọ ti wọn gba wọn fún.

Nigba to n sọrọ, Abubakar sọ pé àwọn èèyàn naa gbọdọ f'ara jin lati sìn ilu wọn leyikeyi ibi ti ori ba da wọn sì, ati pe ijọba ko ni faaye gba awọn iwa to lè tapa si ofin wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI