IFORUKỌSILẸ ẸGBẸ ÒṢÈLÚ APC NI KWARA, IGBIMỌ KOTẸMILỌRUN LÁWỌN ṢETAN LATI GBỌ GBOGBO ẸSUN PATAPATA FUN ÀTÚNṢE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 17, 2021

IFORUKỌSILẸ ẸGBẸ ÒṢÈLÚ APC NI KWARA, IGBIMỌ KOTẸMILỌRUN LÁWỌN ṢETAN LATI GBỌ GBOGBO ẸSUN PATAPATA FUN ÀTÚNṢE


Igbimọ kotẹmilọrun fún ẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ṣetan lati gbọ onírúurú ẹsun tàwọn eeyan fi kan eto iforukọsilẹ to waye laipẹ yii.

Ninu atẹjade ti alaga igbimọ naa ti wọn pe ni Membership Registration Appeal Committee, Oloye Victor Giadom fi sita lo ti ṣàlàyé b'awọn eeyan ṣe gbe ẹsun oríṣiríṣi jade nipa eto iforukọsilẹ to waye naa.

Oloye Giadom sọ pe awọn ṣetan lati gba gbogbo ẹsun wọlé lasiko yii lati mọ awọn igbesẹ to kan lati gbe fun atunṣe to bá yẹ lati ṣe.

Siwaju si i lo sọ pe ki àwọn to ba fẹẹ fi ẹhonu wọn han tete fi ranṣẹ si ileeṣẹ wọn to wa ni 40, Blantyre Street, Wuse 2, Abuja ko to o to ọjọ kẹtalelogun oṣù yii tabi ki wọn fi lẹta ranṣẹ sori imeeli [email protected] ko to to ojo naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI