Ẹ SỌ EDE YORÙBÁ DI DANDAN LÁWỌN ILE ẸKỌ GIGA - ÀÀRẸ ỌNA KAKANFO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 17, 2021

Ẹ SỌ EDE YORÙBÁ DI DANDAN LÁWỌN ILE ẸKỌ GIGA - ÀÀRẸ ỌNA KAKANFO


Ààrẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yorùbá, Iba Gani Adams ti gba gbogbo awọn Gomina ilẹ Yorùbá lamọran lati sọ imọ ẹkọ ede Yorùbá di dandan gẹgẹ bi ohun ti wọn yoo maa lo lati gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sile ẹkọ giga fasiti, poli ati kọlẹẹjì.

Iba Gani Adams lo sọrọ náà laipẹ yìí nilu Ibadan nibi to ti jẹ alaga nibi eto ti ileeṣẹ to n ri sọrọ aṣa ati irin ajo afẹ gbe kalẹ, akọkọ iru ẹ ti wọn pe ni Omituntun Pacesetters Cultural Tourism Festival.

O ni k'awọn gomina ilẹ Yorùbá kan an nipa lati sọ imọ ẹkọ ede Yorùbá di ọkan lara awọn amuyẹ lati wọ ile ẹkọ giga to jẹ ti ijọba pẹlu erongba lati ma jẹ ki ede Yorùbá di ohun igbagbe pátápátá.

Iba Gani Adams ni bi ede Oyinbo ṣe ṣe pataki naa ni ede Yorùbá ṣe pàtàkì, to si lo gbọdọ jẹ dandan fun gbogbo awọn akẹkọọ nile ẹkọ girama.

O ni bi akori ayẹyẹ naa ṣe jẹ 'Aṣa Wa...Ipilẹ Wa' ni nnkan lati ṣe pẹlu iru aṣọ ti ẹya kan gbọdọ maa wọ, ede ti wọn n sọ, at'awọn nnkan mi in to ṣe pataki si ẹya naa, paapaa ounjẹ wọn tó yàtọ̀ tàwọn yòókù fi han pe wọn mọ nnkan ti won gbe dani.

Siwaju si i lo sọ pe lara àwọn ipenija to n koju àwùjọ Yorùbá ni bi wọn se pa awọn nnkan ajogunba bi àṣà àti ìṣe wọn ti sẹgbẹ kan, to si loun gan an lo n fa ai si iṣọkan ati ai ni ifọwọsowọpọ.

Ninu ọrọ rẹ siwaju si i lo sọ pe "Gẹgẹ bi a ṣe ni ede Gẹẹsi ati ìmọ iṣiro, ede Yorùbá naa gbọdọ jẹ dandan lati jẹ ohun àmúyẹ lati fi wọlé sile ẹkọ giga to jẹ ti ijọba. Eyi yóò jẹ k'awọn akẹkọọ wa ni itara lati kọ ede Yorùbá lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ. 

"Ede Yorùbá gbọdọ wa ninu ilana eto Ẹkọ, awọn akẹkọọ paapaa awọn olukọ ti wọn n kọ èdè Yorùbá gbọdọ mu un lokunkundun."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI