Ijọba Kwara pèsè àga ìjokòó àti tábìlì f'awọn ile ẹkọ tó lè l'aadọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 24, 2021

Ijọba Kwara pèsè àga ìjokòó àti tábìlì f'awọn ile ẹkọ tó lè l'aadọta


Ko din ni mèrinlelaadọta awọn ilé ẹkọ ìjọba ti Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fún ni àga ìjokòó àti tábìlì ikọwee, pẹlu èròngbà lati jẹ ki eto ẹkọ rọrùn fún gbogbo àwọn akẹkọọ patapata.

Ile ẹkọ mẹrinlelaadọta ni ijọba ipinlẹ naa pèsè àga àti tábìlì náà, ta a si gbọ pé káàkiri ijọba to wa n'Ipinlẹ náà ni wọn yóò ti jẹ anfààní yii.

Akọwe ijọba nileeṣẹ to n ri soro eto ẹkọ, Arabinrin Kẹmi Adeọṣun to ṣ'oju Gomina AbdulRazaq lati ṣe ìfilọ́lẹ̀ awon àga náà sọ pé èyí yóò jẹ k'awọn akẹkọọ le jẹ igbadun eto òṣèlú awa-ara-wa.

Ààrẹ ẹgbẹ àwọn ọgá ilé ẹkọ gírámà, ìyẹn All Confederation of Principals of Secondary Schools (ANCOPSS), n'Ipinlẹ Kwara, Alaaji Toyin Abdullahi gbe oṣuba kare fún ìjọba, to sì láwọn mọ riri ijọba náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI