Ewe sun'ko: Wọn ti pa olori awọn ọmọ ogun IPOB danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 24, 2021

Ewe sun'ko: Wọn ti pa olori awọn ọmọ ogun IPOB danu


Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹ-èdè yii, to fi mọ awọn ọmọ ogun, fijilante at'awọn mi in ti ṣeku pa olori awọn ọmọ ogun ajijagbara ti ilẹ Ibo, ìyẹn Indegeneous People of Biafra, IPOB Militias, ẹni t'ọpọ awọn èèyàn mọ si Ikonso Commander danu.

Aarọ oni ti í ṣe Satide Abamẹta la gbọ ileeṣẹ ọlọpaa, ileeṣẹ ologun, ìkọ ọtẹlẹmuyẹ at'awọn fijilante gba abule Awomama to wa ni ijọba ibilẹ Oru East, ipinlẹ Imo lo, ìyẹn nibi to jẹ olú ileeṣẹ awọn IPOB naa.

A gbọ pé àwọn ọmọ ogun IPOB naa ni wọn lọ sí ilu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Imo ati ọgbà ẹwọn ipinlẹ naa l'ọjọ karun ùn oṣù yii, nibi ti wọn ti p'awọn ọlọpaa, ti wọn sì tún ṣí gbogbo àwọn ẹlẹwọn silẹ lati salọ.

AWIKONKO gbọ pé b'awọn ìkọ ologun ṣe dé buba awọn eeyan naa la gbọ pé wọn ti ṣina bọlé fún wọn, ti wọn sì láwọn náà dà a pada loju ẹsẹ.

Fún bí ọpọlọpọ wakati la gbọ pé wọn fi kọjú ìbọn sira wọn, ti wọn sì mú olori wọn balẹ níbẹ. Awọn yooku la gbọ pé wọn na papa bora nigba ti wọn ri í pé olórí wọn at'awọn mẹfa kan ti gba èkuru jẹ lọwọ ẹbọra.

Olori wọn yii, ìyẹn Commander Ikonso la gbọ pé wọn n pe ni igbakeji Ààrẹ wọn nínu ija ominira ti wọn n já.

Yatọ sí oku Ikonso ati tàwọn mẹfa ti wọn gbé kúrò níbẹ, wọn tun gba ìbọn AK47 mẹfa, oríṣiríṣi ìbọn àti ọta ibọn, to fi mọ aṣọ ayẹta to wọ s'ara

Ọlọpaa mẹta, ọmọ ogun kan ti wọn fi ara gba ọta ni wọn n l'ọsibitu nibi ti wọn ti n gba ìtọjú lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI