Gendekunrin kan to pe orukọ ara rẹ ni 'Feddes' l'ori ikanni ayelujara ti Twitter lo ti f'ẹsun jibiti kan agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic party, Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọdiyan, to si l'oun ri asiko yii lati s'ọrọ naa sita.
Feddes to l'oun pẹlu ẹnikan to pe ni Henry Obodozie, ẹni to pe orukọ rẹ ni Malik Shabbazz Abdulmalik l'ori ikanni ayelujara ti fesibuuku, ati Nimrod l'ori Twitter l'awọn jọ ṣiṣẹ naa, eyi to ni Ọlọgbọdiyan naa mọ nipa ẹ.
Ninu ọrọ tokọ s'ori Twitter rẹ, Feddes sọ pe "Mo ti fẹẹ s'ọrọ yii jade tipẹ. N'igba ti mo maa kọkọ pade ẹ (Nimrod Henry Obodozie), o ni ki n ba oun wa ounjẹ aja ati aloku ounjẹ alaran (Noodles). Ibaṣepọ akọkọ lọ daadaa, ibaṣepọ keji lo waye l'aaarin oṣu kẹta ọdun to kọja, eyi ti a jọ ṣe adehun si ẹgbẹrun mejilelogun (N22,000) naira ti mi o ti i gba owo naa di asiko ti mo n s'ọrọ yii. A tun ṣe ibadowopọ mi in lẹyin ẹ, to si lọ daadaa.
"Ṣugbọn n'igba to di inu oṣu kejila ọdun 2020, mo pin aworann awọn aja oyinbo kan ti wọn n pe ni Rottweiler, ẹni naa si sọ pe oun yoo fẹ ki n ko meji ninu awọn aja naa wa s'ọdọ agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Kọla Ọlọgbọdiyan.
"Mo lọ ba ọkunrin naa l'ọjọ keji, a si jọ lọ s'ile Ọgbẹni Ọlọgbọdiyan lati ko awọn ọmọ aja naa fun un, akọ kan ati abo kan l'awọn ọmọ aja naa, eyi ti owo wọn jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an (N180,000) naira.
"Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (N100,000) naira to tun din l'ẹgbẹrun meji naira ni Ọgbẹni Ọlọgbọdiyan ko fun mi l'oju ẹsẹ, to si l'oun yoo fun mi l'owo yooku l'ọjọ keji, ṣugbọn ti mi o ri owo naa gba. Iyawo ẹ tun pe mi wi pe ki n ba wọn wa eroja isebẹ aladiẹ, ti mo si ba wọn ra a, ṣugbọn ti wọn ko ti i fun mi l'owo mi to ku d'onii.
"L'atigba naa, mo ti bẹ awọn mẹtẹẹta l'ori foonu wi pe ki wọn san owo mi. Mo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si wọn, ṣugbọn ti wọn ko da mi l'ohun titi d'asiko yii.
"Nimrod mọ bi mo ṣe n tiraka, ṣugbọn ileri asan lo n ṣe fun mi l'atigba naa. Eyi to ba mi l'ọkan jẹ pupọ ni ti gbajugbaja agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti ko san ẹgbẹrun lọna ọgọrin (N80,000) naira to jẹ mi l'atigba naa. Ko gbe awọn ipe mi, bẹẹ si ni ko da awọn atẹjiṣẹ mi pada. Iyawo Ọlọgbọdiyan naa ko gbe ipe mi, bẹẹ si ni ko da awọn atẹjiṣẹ mi pada titi d'onii."
Yatọ eyi, Feddes tun f'ẹsun jibiti kan awọn kan to pe ni DoctorEmto l'ori Twitter, ẹnni to lo jẹ oun ni idaji miliọnu naira ati GhenhisKhan to jẹ oun ni ẹgbẹrun mejilelọgọrun (102,000) naira laaarin ọdun kan.
No comments:
Post a Comment