Lẹyin ti Sanwo-Olu da ọlọpaa ti wọn lu l'ọla, awọn ọmọ Naijiria naa tun da obitibiti owo fun un - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, April 20, 2021

Lẹyin ti Sanwo-Olu da ọlọpaa ti wọn lu l'ọla, awọn ọmọ Naijiria naa tun da obitibiti owo fun un


Ọlaide Ọṣinuga, Lagos
 
Ko si ọrọ meji t'awọn eeyan n mu s'ẹni kaakiri orilẹ-ede Naijiria, paapaa agbaye l'asiko yii bi ko ṣe ti ọrọ ọlọpaa kan, Sunday Erhator ti wọn ni ẹnikan to ṣe s'ofin irinna l'Ekoo, Victor Ebhomenyen fẹẹ lu l'ọsẹ to kọja yii, ṣugbọn ti ko ba a ja pẹlu wi pe o tun gbe ibọn dani.
 
Fọnran iṣẹlẹ naa lo gba gbogbo ori ikanni ayelujara l'ọsẹ to kọja, to si wu awọn eeyan l'ori gidi wi pe ọlọpaa naa mọ iṣẹ rẹ n'iṣẹ, o si yatọ s'awọn ọlọpaa ti wọn n gba owo riba kaakiri igboro.
 
Ko pẹ ti iṣẹlẹ yii to Gomina Sanwo-Olu t'ipinlẹ Eko l'ọwọ lo ti ni ki wọn lọ ọ pe ọlọpaa naa wa f'oun, to si da a l'ọla rẹpẹtẹ.
 
Lẹyin eyi la tun gbọ pe awọn araalu ti wọn gbọ si iṣẹlẹ, ti iwa ọlọpaa naa si tẹ wọn l'ọrun bẹrẹ si da owo fun ọlọpaa yii.
 
Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ugo Egbujo lori ikanni ayelujara ti fesibuuku la gbọ pe o bẹrẹ eto ẹdawo naa l'ọjọ Aiku ti i ṣe Sande ijẹta, ta a si gbọ pe owo ti ko din ni idaji miliọnu naira l'awọn ọmọ Naijiria ti da lati fi ta ọlọpaa l'ọrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI