Ọwọ ọlọpaa Ghana te ẹlẹwọn mẹsan-an to salọ ni Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 20, 2021

Ọwọ ọlọpaa Ghana te ẹlẹwọn mẹsan-an to salọ ni Naijiria


Ọla Eyitayọ, Ọyọ
Mẹsan-an awọn ẹlẹwọn ti wọn salọ kuro l'orilẹ-ede Naijiria l'ọwọ ọlọpaa ti tẹ l'orilẹ-ede Ghana laipẹ yii. Awọn ọlọpaa orilẹ-ede Ghana lo r'ọwọ to wọn l'agbegbe Ada Foah l'asiko ti wọn n na papa bora.
 
Ọga ọlọpaa ẹkun Ada t'ọwọ ti tẹ awọn ọdaran naa, Francis Somian la gbọ pe wọn ta l'olobo n'ipa awọn eeyan naa, to si sare lọ si Clinic Junction Lorry Station, n'ibi to ti lọ ko gbogbo wọn. 
 
AWIKONKO gbọ pe awọn to ileeṣẹ ọlọpaa naa l'olobo sọ pe irin awọn eeyan naa ni i fura si, ati pe oju wọn jọ oju awọn ẹlẹwọn lo jẹ ki wọn tete gbera lọ sibẹ.
 
Ori omi kan ti wọn pe ni River Volta ni wọn gba wọ Ada Foah naa, pẹlu erongba lati maa gba ibẹ lọ silu Accra pẹlu bọọsi akero ti wọn fẹẹ wọ. 
 
Awọn naa ni wọn pe orukọ wọn ni: Emmanuel Obinnah Chiedozie, ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn; Steve Eyenuku, ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn; Enebeli Lucky, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn; Yommi Usmah, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn; Keli Ekureni, ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn; Freedom Yusuf, ọmọ ọdun marundinlọgbọn; Obi Onuora, ọmọ ọdun mejidinlogoji; Patrick Chanar, ọmọ ọdun mẹtadinlaadọta ati Bless Eyenuku toun naa jẹ ọmọ ọdun marundinlọgbọn. 
 
Awọn ọlọpaa jẹ ko ye wa pe n'igba t'ọwọ tẹ awọ eeyan naa, ọwọ orilẹ-ede Naijiria ati ti orilẹ-ede Ghana ni wọn ba l'ara wọn, to fi mọ kaadi idanimọ, iwe irinna at'awọn ohun ini wọn.
 
Bẹ o ba gbagbe, l'ọjọ karun-un oṣu yii ni iroyin jade sita wi pe ẹlẹwọn ti ko din ni 1,844 ni wọn sa jade l'ọgba ẹwọn ipinlẹ Imo to wa n'iluu Owerri.
 
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ irinna l'orilẹ-ede yii, iyẹn Nigerian Immigration Service naa ti wa a gbe ọrọ sita wi pe loootọ l'awọn ti gba awọn ọdaran t'ọwọ tẹ yii pẹlu fọto, orukọ ati kaadi idanimọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI