Pasitọ Adeboye ṣabẹwo s'ijọba ipinlẹ Ekiti, o gbàdúrà fún ìjọba at'awọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 18, 2021

Pasitọ Adeboye ṣabẹwo s'ijọba ipinlẹ Ekiti, o gbàdúrà fún ìjọba at'awọn aráàlú


Aláṣẹ ati olórí ìjọ ìràpadà, ìyẹn The Redeemed Christian Church of God káàkiri agbaye, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti ṣe abẹwo si Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti lori ọrọ eto aabo.

Ana ti i ṣe Satide ni Pasitọ Adeboye ṣe abẹwo naa, to si loun wa lati gbadura fun ìjọba at'awọn ọmọ ati olùgbé ipinlẹ naa ni ile ìjọba to wa ni Oke-Ayaba nilu Ado-Ekiti.

Baba Adeboye ni ìgbàgbọ oun ni pe gbogbo ijinigbe ati ipaniyan to n ṣẹlẹ lasiko yii lorile-ede Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba lọwọlọwọ ni yoo to o d'ohun igbagbe patapata.

Iyawo Gomina Fayẹmi, Erelu Bisi Fáyẹmí; Kọmiṣanna fun eto idajọ, Ọlawale Fapohunda; olori àwọn oṣiṣẹ ìjọba, Arabinrin Peju Babafẹmi; olori àwọn oṣiṣẹ gomina, Ọgbẹni Biọdun Ọmọlẹyẹ; Pasitọ Gike Kuti ti ijọba Ridiimu ati ajagun-fẹyinti Abayọmi Oloniṣakin to fi mọ awọn mi in ni wọn wa nibi ipade naa.


Níbẹ ni Pasitọ Adeboye ti kanminu lori bi wọn ṣe ji àwọn ọba gbe n'ipinlẹ naa, to si ni aibọwọ fun ori ade ati ipo ọba lo fa iru iwa buruku bẹẹ.

O jẹ ko di mímọ pe òun pẹlú ìjọ naa ko ni i dẹkun lati maa gbadura fún ipinlẹ Ekiti lóòrèkóòrè.

Nigba toun naa n sọrọ, Gomina Kayọde Fayẹmi dupẹ gidigidi lọwọ Baba Adeboye fun abẹwo rẹ, to sì ni ipinlẹ naa nilo adura gidigidi lasiko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI