Abiọdun, AbdulRazaq ba Buhari kẹdun iku Attahiru - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 23, 2021

Abiọdun, AbdulRazaq ba Buhari kẹdun iku Attahiru

Gomina ipinlẹ Ogun ati Kwara, Dapọ Abiọdun ati AbdulRahman AbdulRazaq ti ba Aarẹ Muhammadu Buhari k'ẹdun iku olori awọn ologun orilẹ-ede yii, Jẹnẹra Ibrahim Attahiru to padanu ẹmi ẹ l'ojiji nibi ijamba ọkọ ofurufu agberapa to jabọ laipẹ yii n'ilu Kaduna.

Awọn gomina naa sọ pe adanu nla n'iku Attahiru naa jẹ l'asiko fun gbogbo ọmọ Naijiria, tori pe asiko ti orilẹ-ede nilo rẹ ju ni iku da ẹmi rẹ legbodo.
 
AbdulRazaq ninu ọrọ rẹ sọ pe "Fraide Dudu ni ọkọ ti Attahiru jẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria. Ọjọ naa yoo wa titi lai ninu itan, ti yoo si jẹ ọjọ manigbagbe t'awọn eeyan yoo maa ranti wi pe awọn padanu awọn akọni nla.

"L'orukọ awọn ọmọ ati ijọba Kwara, mo n ba Aarẹ Muhammadu Buhari k'ẹdun iku olori awọn oṣiṣẹ ologun ati gbogbo awọn oṣiṣẹ ologun patapata lapapọ wi pe Ọlọrun yoo rẹ wọn l'ẹkun."
 
Dapọ Abiọdun ninu ọrọ tiẹ sọ pe "Ko ni i ṣe pẹlu ọjọ ori wọn, wọn ti sin orilẹ-ede yii tọkan-tọkan, iku ojiji airotẹlẹ wọn jẹ ibanujẹ ati adanu nla."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI