Iyawo kẹrin ni Olanṣhile, tori owu lo ṣe gun ọkọ rẹ pa n'Ijẹbu-Ode - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, May 24, 2021

Iyawo kẹrin ni Olanṣhile, tori owu lo ṣe gun ọkọ rẹ pa n'Ijẹbu-Ode


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Ki lo ṣẹlẹ lọrọ to n jade lẹnu awọn eeyan nilu Ijẹbu Ode nigba ti wọn gbọ pe iyale ile ẹni ọdun mọkanlelaadọta kan, Olanshile Nasirudeen gun ọkọ rẹ pa.
 
Ọlanshile ni iyawo kẹrin ti ọkọ rẹ maa fẹ sile gẹgẹ ba a ṣe gbọ. Iṣẹ alapata l'awọn mejeeji si jọ n ṣe l'odo ẹran kan to wa n'ilu Ijẹbu Ode.
 
Wọn ni ṣe ni ọkọ Ọlanshile fun obinrin kan l'oyun, eyi ti wọn ni iyaale ile yii ti n gbọ finrinfinrin rẹ tẹlẹ. Aipẹ yii ni wọn ni obinrin ti ọkọ Ọlanṣhile fun l'oyun lọ ba wọn ni odo ti wọn ti n pa ẹran, bi Ọlanṣhile si ṣe ri obinrin naa lo ti bẹrẹ si i ba a fa wahala.
 
Ibi twahala naa ni ọkọ Ọlanṣhile ti lọ ba wọn lati pẹtu si Ọlanṣhile ninu, ṣugbọn kaka ni obinrin naa gbọ, ṣe lo ki ọbẹ ẹran mọlẹ, to si fi ge ọkọ rẹ l'ẹsẹ.
 
Ere ni wọn kọkọ pe e, afi bi ọkunrin naa ṣe ṣubu lulẹ, to si ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI