Adura itunu Aawẹ maa waye ni Mọṣalaṣi apapọ orilẹ-ede yii - Awọn alaṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, May 12, 2021

Adura itunu Aawẹ maa waye ni Mọṣalaṣi apapọ orilẹ-ede yii - Awọn alaṣẹ


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Awọn alaṣẹ ati alakoso mọṣalaṣi agba orilẹ-ede yii to wa n'ilu Abuja, iyẹn Abuja National Mosque ti sọ pe adura ipari aawẹ Ramadaani maa waye ninu mọṣalaṣi naa, yala l'onii ti i ṣe Ọjọru tabi ọla Ọjọbọ, iyẹn Tọside, bẹrẹ lati aago mẹsan-an aarọ.
 
Agbẹnusọ fun Mọṣalaṣi apapọ naa, Haliru Shuaibu lo s'ọrọ naa n'irọlẹ ana, Tusidee wi pe bo ba ṣee ṣe b'awọn ba ri oṣupa ki ilẹ ana to o ṣu, adura naa yoo waye lonii, ṣugbọn t'awọn ko ba ri i, ọla l'awọn yoo ṣe adura naa.
 
Shuaibu sọrọ yii l'ẹyin ipade to ṣe pẹlu minisita f'ọrọ ilu Abuja, Mallam Bello at'awọn agbaagba Imaamu, to fi mọ awọn alẹnulọrọ l'ẹka eto ilera.
 
O ni inu mọṣalaṣi naa ati ayika rẹ l'awọn yoo ti ṣe adura yii, to si lo o ni i ṣe pẹlu igba t'awọn ba fi ri oṣupa.
 
Bakan naa lo sọ pe ki gbogbo awọn ba n bọ lati wa s'ibi adura naa mura ni ibamu pẹlu ọna lati dena ajakalẹ Korona to wa n'ita l'asiko yii.
 
O si tun jẹ ko di mimọ pe gbogbo eto lo ti pari lori ọrọ eto aabo n'ibi adura naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI