Ẹ ye e binu Ààrẹ Buhari lai nìdí, ẹ dẹkun láti máa sọrọ rẹ laida - AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 12, 2021

Ẹ ye e binu Ààrẹ Buhari lai nìdí, ẹ dẹkun láti máa sọrọ rẹ laida - AbdulRazaq


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wí pé kí wọn máa bọwọ to ba tọ sí Ààrẹ orílẹ-èdè yii, Muhammadu Buhari tori pe o l'ẹtọ sí í.

O ni ko yẹ kawọn to n sọ isọkusọ dẹkun láti máa sọrọ rẹ laida, tori pe ko sí nnkan tàwọn ọmọ Nàìjíríà n fẹ, ti ko ṣe fún wọn.

Laipẹ yii ni AbdulRazaq sọrọ náà jáde, to sí ní Ààrẹ Buhari gẹgẹ bí aṣáájú tí ṣe púpọ ninu ọrọ idagbasoke orilẹ-ede Naijiria, to si lo o nilo k'awọn eeyan maa b'ọwọ fun un gẹgẹ bi aṣaaju ati adari.
 
N'ibi to ti pin ounjẹ ọdun f'awọn araalu ti wọn ni ipenija ara, awọn alaini, to fi mọ awọn opo ni Gomina ti sọrọ yii, iyẹn n'ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI