Agbẹ mẹta l'Ọṣun kagbako awọn Fulani darandaran ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, May 9, 2021

Agbẹ mẹta l'Ọṣun kagbako awọn Fulani darandaran ni Kwara


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Kani ki i ṣe ọpẹlọpẹ ori to ko awọn agbẹ mẹta kan ti wọn n pe n'ijọba ibilẹ Odo-Otin to wa n'ilu Ọyan, ipinlẹ Ọṣun yọ l'ọwọ iku ojiji ni, boya wọn ko ba ti d'ero ọrun alakeji l'ọjọ Satide ana, iyẹn Abamẹta. 
 
Wọn ni ṣe l'awọn Fulani darandaran kan lọ ọ kọlu awọn agbẹ naa ninu oko wọn, ti wọn si lu wọn l'alubami.
 
Awọn agbẹ naa ti wọn sọ pe t'ẹgbọn t'aburo ni gbogbo wọn ni wọn pe orukọ wọn ni: Ọpẹyẹmi Joseph, Nathaniel Joseph ati Friday Joseph.
 
A gbọ pe ṣe l'awọn Fulani naa n fi maalu wọn jẹ oko awọn mẹtẹẹta to wa ni Afọyin, Erin-Ile n'ipinlẹ Kwara l'asiko ti wọn debẹ, ti wọn si l'oju ẹsẹ ni wọn ti n bẹ wọn lati ko maalu wọn kuro nibẹ.
 
Nnkan bi aago meje irọlẹ n'iṣẹlẹ naa waye, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.
 
Wọn ni kaka k'awọn Fulani naa ko awọn maalu wọn kuro, ṣe ni wọn yọ kumọ ti wọn, ti wọn si bẹrẹ si i fi lu wọn, titi ti wọn fi lu wọn l'ori fọ danu.
 
Ere la gbọ pe awọn mẹtẹẹta ba kuro nibẹ, ti wọn si gba aafin ọlọyan t'ilu Ọyan lọ, Ọba Kelani Adekẹyẹ ti wọn si ni ṣe ni Kabiyesi naa da wọn pada wi pe ki wọn lọ ọ f'ẹjọ sun Ọba Elerinle at'awọn ọlọpaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI