Kwara: AbdulRazaq b'awọn agbaagba ṣinu aawẹ Ramadaani - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 9, 2021

Kwara: AbdulRazaq b'awọn agbaagba ṣinu aawẹ Ramadaani


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'ọjọ Ẹti-Furaidee ana ti ba gbogbo awọn agbaagba ninu ẹsin Isilaamu ṣinu aawẹ Ramadaani, l'ojuna lati fi ẹmi imoore han si wọn.
 
Ana ti i ṣe Furaidee ni ọjọ Ẹti to gb'ẹyin ninu aawẹ Ramadaani to n lọ l'ọwọ yii, eyi ti yoo pari l'ọsẹ tuntun ta a ṣẹṣẹ wọnu rẹ yii.
 
Gbọngan ayẹyẹ t'ipinlẹ naa, iyẹn Kwara State Banquet Hall to wa n'ilu Ilọrin ni eto naa ti waye. 

A gbọ pe b'awọn ẹlẹsin musulumi e wa nibẹ naa l'awọn ẹlẹsin kristẹẹni naa pọ nibẹ pẹlu lati jọ jẹ, ti wọn si tun jọ mu.
 
L'ara awọn to wa n'ibẹ ni: Igbakeji gomina, Kayọde Alabi; abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnọrebu Danladi; alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Alaaji Abdullahi Samari; Ọnọrebu  Ọlawọyin Magaji; akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamman Saba Jibril ati aṣoju Naijiria s'ilẹ Malaysia, Amb. Nurudeen Mohammed.

Awọn mi in ni: Sẹnetọ Ahmed Mohanmed; Sẹnetọ Sulaiman Ajadi; Sẹnetọ Simeon Ajibọla; Oloye  James Ayeni; Alaaji Kunle Sulyman; Oloye Rex Ọlawọye; Alaaji LAK Jimoh; Alaaji Abubakar Ndakene; Alaaji Shogo;  Alaaji Mayaki ati Alaaji Baba Podo. 

Bakan naa l'awọn bi i Oloriewe Raheem Adedoyin, Alaaji Alhassan Bagudu, Ọmọwe Mohammed Ghali, Ọjọgbọn Shehu Adaramaja, Ọnọrebu Abdulmumini Katibi ati Alaaji Ganiyu Galadima ko gbẹyin nibẹ.

Architect Saifudeen, Alaaji Alakawa, Alaaji Bashir Adigun, Alaaji Saadu Salahudeen, Alaaji Rasaq Jiddah naa wa nibẹ.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI