Awọn alaimọkan lo n fẹ ki ilẹ Yoruba da duro - Arabambi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, May 3, 2021

Awọn alaimọkan lo n fẹ ki ilẹ Yoruba da duro - Arabambi


Alaga ẹgbẹ oṣelu Labour n'ipinlẹ Ogun, Kọmureedi Abayọ Arabambi ti sọ pe gbogbo awọn to n fẹ ki orilẹ-ede Naijiria pin, ti wọn si n fẹ idaduro ilẹ Yoruba lo jẹ pe iranlọwọ ni wọn wa kiri lati gba iwe igbelu orilẹ-ede ti wọn fẹẹ lọ.
 
Laipẹ yii ni Kọmureedi Arabambi s'ọrọ naa l'asiko to n ba akọroyin s'ọrọ n'ilu Abẹokuta ti i ṣe ipinlẹ Ogun.
 
O ni pupọ awọn to n fẹ idaduro ilẹ Yoruba lo jẹ pe wọn ti gba iwe irinna, ti wọn si n wa aabo l'awọn orilẹ-ede ti wọn n wa ojurere iwe igbelu si.
 
Arabambi sọ pe ilẹ Yoruba ti kopa ribiribi ninu idagbasoke Naijiria ju ki wọn pin l'asiko to yẹ ki wọn maa jeere iṣẹ rere wọn lọ, to si l'awọn ko ṣetan lati tẹle awọn to n fẹ ki Naijiria pin lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI