Eyi ni bi Bàbá Ìjèṣà ṣe sọ àsọtẹlẹ wahala to ko ara rẹ si - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, May 2, 2021

Eyi ni bi Bàbá Ìjèṣà ṣe sọ àsọtẹlẹ wahala to ko ara rẹ si


Lati nnkan bi ọsẹ kan sẹyìn báyìí ni ọrọ gbajugbaja òṣèré tíátà nni, Ọgbẹni Ọlanrewaju James Omiyinka ti ọpọ awọn èèyàn mọ sí Bàbá Ìjèṣà ti di àríyànjiyàn láàárín àwọn èèyàn.

Ọmọdebinrin ọmọ ọdún mẹrinla kan la gbọ pé Bàbá Ìjèṣà n fi ọwọ pa lára lati ba a laṣepọ, bo tilẹ jẹ pé kò bá a laṣepọ.

Titi di asiko ta a pari ìròyìn yìí ni Bàbá Ìjèṣà sí wá lahamọ àwọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, nibi to ti n duro dè ìdájọ ile ẹjọ.

B'awọn kan ṣe n sọ pé iwa ti Bàbá Ìjèṣà hu ku diẹ kaato, bẹẹ láwọn kan n sọ pé ọrọ rẹ ki í ṣe oju lasan, tàwọn mi in sí n sọ pé pampẹ ayé lo kò sí.

Laipẹ yii ni Bàbá Ìjèṣà kopa ninu fiimu kan ti wọn pe ní 'ILU AWỌN OBINRIN', Àìgbọràn to ko o sí wahala ninu fiimu naa lo tun pada ṣẹlẹ sí í loju ayé.

O ṣee ṣe ká ní Bàbá Ìjèṣà ti tẹlẹ awọn amọran to wa ninu fiimu naa ni, o ṣee ṣe kí eyi tó n ṣẹlẹ sí í lọwọ yii ma pada waye rara.

Ninu fiimu naa, orukọ Ololomasun ni Bàbá Ìjèṣà n jẹ ninu fiimu naa, to sì jẹ pé gbogbo obinrin lo n ba laṣepọ ninu fiimu yii. Lẹyin-o-rẹyin ni Bàbá Ìjèṣà pada kò sí wahala nla nipa awọn obinrin to n ba laṣepọ karakara.

Ọkan lara awọn ti wọn jọ kopa ninu fiimu yii ni Bàbá Ìjèṣà n gba lamọran pé ko jáwọ, ko ma ba a kò sí irú wahala toun ko sí.

Òṣèré náà béèrè lọwọ Bàbá Ìjèṣà ninu fiimu yii wí pé "Ki lo sun ẹ de'bẹ?"

Bàbá Ìjèṣà da a lohun pe "Bi ẹ ṣe rí mi yii, agbalagba oniṣina ni mi o. Nibi ti mo ti wa, ko sẹni tó lè purọ fún mi. Ko si obinrin to ka mi mọ ri. Ololomasun ni orúkọ inagijẹ ti wọn n pé mi, orukọ yẹn sí ni wọn máa n fún àwọn ọkùnrin oniṣina.

"Ọlọrun ló mú mi. Nipasẹ awọn obinrin kan ti mo n ṣe agbere pẹlu ni mo ti lù magun. Níbẹ ni wọn ti sáré gbe mi lọ sọdọ alaanu pasitọ kan. Pasitọ yii lo gb'adura fún mi, ti ara mi fi ya. Lẹyìn tí ara mi ya tan, pasitọ náà sọ pé kí n máa lọ sílé lọ bá àwọn èèyàn mi.
 
"Lóòótọ́ mo ni iyawo, ṣugbọn irọ tí mo máa n pa fún àwọn obìnrin ni pé mi o ti í ni iyawo, bẹẹ sì ni mi o ti í bímọ. Lẹyìn ọjọ keje ni mo kuro lọdọ pasitọ yii, bi mo ṣe n lọ nínú mọto mi ni mo pade ọmọbinrin kan to n seju sí mi.

"Mo ro o lọkàn ara mi pé kí n sáré fi ọmọbinrin náà lata ki n so jáwọ patapata, mi o mọ pé mo ti gegun fún ara mi. Mo kan fẹẹ gbádùn ẹ ki n sí salọ, láì mọ pé mo ti ko si pampẹ."

Púpọ awọn to wo fiimu yii ni wọn n sọ pé kò yẹ ki Bàbá Ìjèṣà ṣe iru nnkan itiju nla to ṣe yii, ati pe o yẹ kó ti fi ọrọ rẹ nini fiimu naa k'ọgbọn fúnra rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI