Awọn ọmọ 'Yahoo' ti ko din l'ọgbọn ti ha n'Ilọrin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 8, 2021

Awọn ọmọ 'Yahoo' ti ko din l'ọgbọn ti ha n'Ilọrin


Ko din ni ọgbọn awọn afurasi ọmọ Yahoo ta a gbọ pe ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu ni Naijiria, EFCC ti tẹ bayii n'ilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara l'Ọjọru, iyẹn Wẹsidee to kọja yii.
 
Awọn agbegbe ọtọọtọ la gbọ pe ọwọ palaba awọn eeyan naa ti segi, iyẹn bi i wakati mẹrinlelogun ti wọn lọ ọ ko awọn akẹkọọ kan ta a gbọ pe awọn naa n ṣiṣẹ Yahoo yii.
 
Wọn lo fẹe jẹ pe gbogbo akẹkọọ ti wọn wa ninu ile ti wọn ti lọ ko wọn ni wọn ko patapata, iyẹn ninu ile awọn akẹkọọ ti wọn pe ni Unigate hostel.
 
Agbẹnusọ ajọ n'ilu Ilọrin,Ọgbẹni Ayọdele Babatunde to gbe ọrọ naa sita sọ pe ọjọ Iṣẹgun Tusidee l'ọwọ awọn eeyan naa kaakiri ilu Ilọrin.
 
O darukọ gbogbo wọn gẹgẹ bi i Adigun Ọladapọ, Ọlamilekan Ogunṣọla, Fuad Abidemi, Haastrup Samuel, Ọlamide Adeyẹmi, Akinọla Abideen, Ebenezer Haastrup, Kẹhinde Adeyẹmi, Quadri Kareem, Abubakar Abdulbashit, Damilọla Akinọla, Ọla-Oluwa Samuel, David Oyewọle, Mojereọla Tọheeb, Isaac Chikezie, Joshua Chikezie, Abdulsalam Ọpẹyẹmi ato Abawọnjọ Abdulazeez.
 
 
Awọn yooku ni Ganiyu Ọlanrewaju, Adeleke Ibrahim, Taiwo Ganiyu, Ọkẹ Gideon, Ọlakunle Adebisi, Ajani Samuel, Joshua Ogizien, Sọdiq Ọlaṣupọ, Ọlamilekan Mubarak, Adeniyi Ọlaṣhile, Rotimi Adẹyẹmi ati Rasaq Ọlanrewaju. 
 
Gbogbo wọn pata la gbọ pe ajọ naa fẹẹ f'oju wọn ba ile ẹjọ l'ẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
 
L'ara awọn nnkan ta a gbọ pe wọn gba l'ọwọ wọn ni Foonu olowo nla l'oriṣiriṣi, mọto bọginni mẹwaa ọtọọtọ, to fi mọ oogun abẹnugọngọ ati awọn ayederu iwe ti wọn fi n lu jibiti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI