Dapọ Abiọdun ko le fi ibo ijọba ibilẹ pa owo wọle - Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, May 7, 2021

Dapọ Abiọdun ko le fi ibo ijọba ibilẹ pa owo wọle - Aderinokun


Akinriyuwa tilẹ Owu, to tun jẹ oludasilẹ ajọ Olumide & Stephanie Aderinokun, Oloye Olumide Aderinokun ti kilọ fun Gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, lati ma ṣe lo ibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna lati pa owo wọle si osuwọn ipinlẹ ọhun.

Ọkunrin naa sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita lati ileeṣẹ iroyin ẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee ana.

O ni ki Gomina atawọn eeyan ẹ ya tete wa ọna mii in lati mu owo wọle yatọ si ti ibo to n bọ yii, nitori ẹgbẹrun lọna igba naira ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira ti wọn pe lowo fọọmu fun ipo alaga ijọba ibilẹ ati kanselọ ki i ṣe ara ẹ rara.

Ọkunrin naa sọ pe "Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) n wa ọna lati ma jẹ kawọn ẹgbẹ alatako kopa ninu ibo to n bọ yii, ti wọn si fẹẹ fara ni wọn, ni wọn ṣe gbe ipinnu ọhun jade. A n sọrọ nipa eto idibo lati sin awọn eeyan wa nigberiko, laiṣe ile igbimọ aṣofin.Ajọ eleto ibo ijọba ibilẹ ko gbọdọ jẹ ibi ta a ti n pa owo wọle’’

Aderinokun tun sọ pe iru igbesẹ yii tun le ko irẹwẹsi bawọn ọdọ lati ma ṣe kopa ninu ibo yii.

A o ranti pe ninu osẹ yii ni alaga fajọ eleto ibo ijọba ibilẹ iyẹn OGSIEC, Babatunde Ọṣibodu, sọ lakooko to n ṣe ipade pọ pẹlu awọn olori ẹgbẹ oṣelu atawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ sọ pe awọn ti yọ kawọn obinrin to ba fẹẹ fije ninu ibo naa klo sanwo ṣugbọn awọn ti wọn jẹ ọkunrin ni yoo san ẹgbẹrun lọna igba ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira fun owo fọọmu lati dije

Satidee, Abamẹta, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje,ọdun yii ni ibo naa yoo waye jakejado ipinlẹ Ogun.

Oloye Olumide to ti wa na ọwọ aanu ẹ sawọn eeyan paapaa julọ ni aarin gungun ipinlẹ Ogun nipaṣẹ ajọ to da silẹ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI