Aye Gbẹgẹ! Ẹ wo ọmọ ọdun mọkanlelogun to lu jibiti biliọnu meji naira l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 26, 2021

Aye Gbẹgẹ! Ẹ wo ọmọ ọdun mọkanlelogun to lu jibiti biliọnu meji naira l'Ekoo


Joshua Dominic, ọmọ ọdun mọkanlelogun lẹ n wo yi o. Oun ni alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Brisk Capital Limited, iyẹn ileeṣẹ ti wọn ti n fi owo dokoowo l'ori ikanni ayelujara, ta a si gbọ pe awọn to le ni ẹgbẹrun kan ni wọn n fi owo wọn dokoowo l'ọdọ rẹ.
 
Pupọ awọn eeyan yii la si gbọ pe bi wọn ṣe n fi owo wọn dokoowo n'ileeṣẹ Brisk Capital Limited to jẹ ti Joshua yii la gbọ pe wọn ki i ri owo wọn gba pada mọ, eyi ti wọn ni baba-nla onijibiti ni.
 
Laipẹ yii l'awọn ti ko din ni ẹẹdẹgbẹta kọ iwe ẹsun lọtọọtọ lati f'ẹsun kan Joshua wi pe ṣe lo n fi orukọ ileeṣẹ naa lu awọn ni jibiti laimọ. Eyi lo fa a ti ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko to n ṣe iwadii jibiti, iyẹn Special Fraud Unit fi gba iṣẹ naa ṣe.
 
Owo to le ni biliọnu meji naira la gbọ pe Joshua, ọmọ ipinlẹ Ebonyi to n fi ilu Uyo n'ipinlẹ Akwa Ibom ṣe ibugbe rẹ gbe salọ.
 
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ẹka ileeṣẹ ọlọpaa naa, DSP Eyitayọ Johnson gbe jade lo ti jẹ ko ye wa pe ori ikanni ayelujara ti Instagram, Facebook ati Linkedin, to fi mọ awọn iwe iroyin lo ti fi n pe awọn eeyan lati wa a dokoowo, to si n lu wọn ni jibiti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI