Idibo Ijọba-Ibilẹ: Oriire nla lo wọle tọ ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ọyọ yi o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Monday, May 24, 2021

Idibo Ijọba-Ibilẹ: Oriire nla lo wọle tọ ẹgbẹ oṣelu PDP l'Ọyọ yi o


Ọla Eyitayọ, Ọyọ
 
Ọjọ manigbagbe l'ọjọ Satide-Abamẹta to kọja yii jẹ f'ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'igba ti ajọ eleto idibo n'ipinlẹ naa, iyẹn Independent Electoral Commission, INEC kede awọn oludije mejilelọgbọn ninu mẹtalelọgbọn s'ipo alaga ijọba ibilẹ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa wi pe wọn jawe olubori.
 
Alaga eto idibo n'ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Isiaka Ọlagunju lo kede naa nilu Ibadan l'ẹyin ti wọn dibo naa tan, to si jẹ ko di mimọ pe ijọba ibilẹ Ido n'ikan nikan ni wọn sun siwaju si Ọjọru, iyẹn Wẹsidee ọsẹ yii.

Lara awọn ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, iyẹn OYSIEC kede wọn ni Raheem Akeem Adepọju (Oorelope), Sulaiman Adediran (Irepo), Arabinrin Juliana Oluwakẹmi Akanni (Ọlorunṣogo), Akanji Kabir Ayọade (Ogbomọṣọ North), Oyeniyi Timothy Oyedokun (Ogbomọṣọ South), ati Olugbenga Ọbalọwọ (Ibarapa East).

Jẹlili Oyinloye Adebare (Iwajọwa), Fasasi Adeagbo (ATISBO), Arabinrin Ramat Adeniran (Saki-East), Sarafadeen Omirinde (Saki-West), Adebare Muraina Afọlabi (Kajọla), Adesoye Ṣeun Ojo (Ogo-Oluwa) ati Bọlaji Ojo Akintọla (Itesiwaju).

Awọn mi in ni Ọlatẹju Michael Alabi (Oriire), Adegbitẹ Isaiah Alabi (Surulere), Adedoyin Oloyede Adeoye (Ibarapa Central), Lateef Adebayọ Lawal (Ibarapa North), Muftau Oṣuọlale (Isẹyin) ati Sunday Akindele Ojo (Afijio).
 
Kafilat Ọlakojọ (Atiba), Musbaudeen Adeṣina Ṣnusi (Ọna-Ara), Babatunde Akeem Salami (Oyo West), Saheed Arowoṣaye Adeyẹmi (Oyo East), Ibrahim Akintayọ (Ibadan North-East) ati Taoheed Jimọh Adedigba (Akinyẹle)

Awọn yooku ni Ọlaide Popoọla (Oluyọle), Kazeem Gbadamọsi (Lagelu), Oyedele Sikiru Sanda (Egbeda), Kẹhinde Adeyẹmi Akanni (Ibadan South-West), Musbaudeen Ṣanusi (Ọna-Ara), Saheed Ọladayọ Yusuf(Ibadan North), ati Emmanuel Oluwole Alawọde (Ibadan South-East).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI