Ẹ tun w'oju awọn afurasi ajinigbe t'ọwọ Amọtẹkun tẹ l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Tuesday, May 11, 2021

Ẹ tun w'oju awọn afurasi ajinigbe t'ọwọ Amọtẹkun tẹ l'Ondo

 
Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
L'ọjọ Aje-Mọnde ana ni ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba, iyẹn Amọtẹkun f'oju awọn ogbologbo afurasi ajinigbe mẹrin kan han f'awọn akọroyin n'ilu Akurẹ, ipinlẹ Ondo.

Yameri Muhammed,  Umar Ali, Abubakar Sidiku ati Usman Garuba l'awọn mẹrin naa ti wọn sọ pe maalu ti wọn n da kaakiri ni wọn fi n b'oju ji awọn eeyan gbe lati gba owo lọwọ wọn.

Agbegbe kan ti wọn pe ni Ọda, iyẹn n'ilu Akurẹ la gbọ pe ọwọ palaba wọn ti segi l'asiko ti wọn fẹẹ gba owo l'ọwọ awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe.
 
Ọga awọn Amọtẹkun n'ipinlẹ naa, Oloye Adetunji Adelẹyẹ n'igba to n f'oju awọn mẹrẹẹrin han jẹ ko ye wa pe okunrin olowo kan l'awọn ajinigbe yii fẹẹ ji gbe, ti wọn ko si ri i ji gbe.
 
Igba ti ọwọ wọn ko dẹ si okunrin olowo naa la gbọ pe wọn pada lọ ọ ji awọn mẹta kan gbe nibi ti wọn sa si lati ya fun ojo to n rọ l'ọwọ.
 
L'ẹyin ti wọn ji awọn eeyan naa gbe ni wọn pe mọlẹbi wọn lati gba owo l'ọwọ wọn, ti wọn si l'awọn mọlẹbi naa ko owo silẹ.
 
Asiko ti wọn fẹẹ gba owo yii l'ọwọ tẹ gbogbo. Nibẹ ni wọn ti gba ibọn pẹlu ada l'ọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI