Eyi ni bi Pasitọ Adeboye ṣe padanu akọbi ọmọ rẹ l'ojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 6, 2021

Eyi ni bi Pasitọ Adeboye ṣe padanu akọbi ọmọ rẹ l'ojiji


'Irọ ni; ko le ṣẹlẹ; ko jẹ jẹ bẹẹ', eyii at'awọn ọrọ iyalẹnu mi in ni wọn lo n jade l'ẹnu pupọ awọn eeyan, paapaa awọn ọmọ ijọ Irapada ti i ṣe Ridiimu kaakiri agbaye n'igba ti iroyin iku ọmọ olori ijọ naa, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, iyẹn Pasitọ Dare Adeboye jade sita.
 
Ana ti i ṣe Wẹside la gbọ pe Pasitọ Adejare, ẹni ọdun mejilelogoji naa jade laye s'ile ẹ to wa n'ilu Eket, ipinlẹ Akwa-Ibọm. Oju oorun la gbọ pe gbajugba pasitọ naa ku si.
 
Iroyin to tẹ AWIKONKO l'owọ fi ye wa pe Pasitọ Dare Adeboye lo waasu nibi ipade kan to waye l'ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee ijẹta.
 
Dare ni igbakeji olori ijọ naa l'ẹkun karundinlogoji ti ijọ naa, iyẹn t'awọn ọdọ.
 
A gbọ pe bo ṣe lọ ọ sun lati fun ara rẹ ni isinmi ni ko le dide mọ. L'oju ẹsẹ ni wọn ti ranṣẹ s'awọn agbaagba ko to di pe wọn fi to baba re, iyẹn Baba Adeboye leti.
 
Iyawo rẹ, Arabinrin Temiloluwa la gbọ pe o pariwo sita n'igba to ri i pe ọkọ rẹ ti ku.
 
Wọn ni ṣe ni obinrin naa sare pe awọm pasitọ to wa n'itosi lati gb'adura fun boya yoo ji dide, ṣugbọn ti wọn sọ pe ẹpa ko boro mọ.
 
A gbọ pe ọkunrin naa ko ṣaisan, bẹẹ si ni ko sọ pe nnkan n ṣe oun ko to o ku l'ojiji.
 
Agbẹnusọ ijọ naa, Pasitọ Ọlaitan Olubiyi to f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ laaarọ oni sọ pe oun ko ti i lọ sọ bo ṣe ṣẹlẹ, ṣugbọn to lo ṣee ṣe k'oun s'ọrọ l'ori ẹ ki ọjọ oni to o lọ.

Oṣu to n bọ la gbọ pe Dare n mura silẹ lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹtalelogoji l'oke eepẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI