Ganiu lu iyawo ẹ, o tun lu iya-iyawo ẹ pa l'Atan Ọta, Ikorodu l'ọwọ ti pada tẹ ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Thursday, May 6, 2021

Ganiu lu iyawo ẹ, o tun lu iya-iyawo ẹ pa l'Atan Ọta, Ikorodu l'ọwọ ti pada tẹ ẹ


Adura ikẹyin t'awọn Musulumi maa n ṣe si oku lara la gbọ pe awọn ara agbegbe Atan-Ọta n'ipinlẹ Ogun n ṣe fun gendekunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Ọpẹyẹmi Adeọla Ganiyu ti wọn lo o lu iya-iyawo ẹ pa l'ọsẹ to kọja yii n'igba t'ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ.
 
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni l'ọjọ kẹta oṣu yii l'ọwọ tẹ Ganiyu nilu Ikorodu to salọ lati farapamọ si l'ẹyin to lu iya-iyawo ẹ naa, Arabinrin Abọsẹde Oyewọle pa.
 
Awọn to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe ṣe ni Ganiyu lu iyawo ẹ lalubami, to si da apa rẹpẹtẹ si i l'ara. Iyawo Ganiyu naa lo lọ fi ẹjọ sun mama rẹ pe ki wọn wo bi ọkọ oun ṣe ṣe oun.
 
Ibinu yii la gbọ pe iya-iyawo Ganiyu, iyẹn oloogbe naa ba de ile Ganiyu lati kilọ fun un. Wọn ni obinrin naa ko ti i wọle ti Ganiyu fi sare pade rẹ, to si lu mama agbalagba naa lalubami.
 
Igba to lu mama yii, to tẹ ara rẹ l'ọrun tan, ni wọn lo o tun lọ yọ ọbẹ, to si fi gun mama naa n'ikun. L'oju ẹsẹ la gbọ pe mama yii ti ṣubu lulẹ, t'awọn eeyan si sare gbe e lọ si ọsibitu lati doola ẹmi ẹ.
 

Ọsibitu ti wọn gbe mama naa lọ la gbọ pe o dakẹ si. Bi Ganiyu ṣe gbọ pe iya-iyawo oun ti jade laye ni wọn lo o ti ba ẹsẹ ẹ s'ọrọ, to si salọ s'ilu Ikorodu n'ipinlẹ Eko lati farapamọ si ki aṣiri rẹ ma ba a tu.
 
Ọkan lara awọn ẹgbọn iyawo Ganiyu, iyẹn Ọdunayọ Mathew lo sare gba teṣan ọlọpaa lọ lati lọ fi ẹjọ sun, ti wọn si ni lati ọjọ Satide ọsẹ to kọja ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ, ọjọ kẹta ti i ṣe Mọnde to kọja yii l'ọwọ palaba ẹ ṣẹṣẹ segi.
 
N'igba tọwọ tẹ Ganiyu ni aṣiri rẹ to o ṣẹṣẹ tu pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun n'ilu Atan Ọta ni, ati pe oun naa wa lara awọn to lewaju lọ ọ dana sun teṣan ọlọpaa Atan Ọta l'ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa ọdun to kọja.
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Awolowo Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn lọ ọ f'oju rẹ ba ile ẹjọ l'ẹyin ti iwadii ba tubọ pari l'ori rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI