Ìdájọ iku lo tọ s'awọn ajinigbe - Awọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Kwara sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 5, 2021

Ìdájọ iku lo tọ s'awọn ajinigbe - Awọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Kwara sọrọ


Gbogbo awọn aṣofin ipinlẹ Kwara pátápátá l'ọjọ Ìṣẹgun ti i ṣe Tusidee to koja yii ni wọn ti n rawọ ẹbẹ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ naa, Abdulrahman Abdulrazaq lati gbe iwe abadofin ti yóò máa dá ẹjọ iku f'awọn ajinigbe n'ipinlẹ naa.

Yatọ sí èyí, awọn aṣofin naa tun gba Gómìnà lamọnran láti ro awọn Ileeṣẹ eleto aabo káàkiri ipinlẹ naa l'agbara nipa fifun wọn láwọn nnkan irinsẹ, pàápàá l'agbegbe Oke-Ero láàárín gbungbun ipinlẹ naa.

Eyi láwọn ọrọ afẹnuko sí nínú ijiroro awọn aṣofin lori ọrọ tó ní í ṣe pẹlú aráàlú, eyi ti wọn pe akori é ni 'Ọna lati d'ẹkun iwa ijinigbe n'ipinlẹ naa', eyi ti Ọnọrebu Abọlarin Ganiyu Gabriel ṣe agbekalẹ ẹ.

Nigba to n ṣe àpẹẹrẹ àwọn ti wọn ti jí gbé, o ni eyi tó ṣẹlẹ loju ọna Obbo-Ile-Aiyegunle-Eruku-Isapa n'ijọba ibilẹ Kwara South l'ọjọ kinni oṣù yii, nibi ti wọn ti yinbọn pa Kọmiṣanna ipinlẹ Kogi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI