Iṣẹ ni wọn rán Wasiu l'Ekoo, lo ba d'awati - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 5, 2021

Iṣẹ ni wọn rán Wasiu l'Ekoo, lo ba d'awati


Lati ọjọ Aiku tí ì ṣe Sande to kọja yii la gbọ pé wọn ti n wa baálé ilé tí ẹ n wo yii, Wasiu Emmanuel Ashafaz, ti wọn kò sí tí ì rí titi dasiko ta a pari ìròyìn yìí.

Ojúlé kejidinlogun, àdúgbò Akinpẹlu to wa ni Ikosi, Ketu nilu Eko la gbo pe Wasiu n gbe.

Mile 12 nilu Eko kan naa la gbọ pé wọn rán Wasiu lọ ní nnkan bi aago mẹjọ aarọ ọjọ náà, ti kò sí tí ì pada sílé.

Wọn ti pé ẹrọ ibanisọrọ rẹ titi, ṣugbọn ti ko lọ, eyi gan an lo jẹ ki wọn pariwo sita pe k'ẹnikẹni to ba kofiri rẹ tete fi to Ileeṣẹ ọlọpaa leti.


Bakan naa ni wọn tún gbé awọn nọmba ibanisọrọ meji kan sita tàwọn èèyàn yóò pé sí bí wọn bá ri í níbikíbi.

Awọn nọmba naa ni: 08035219488 ati 08167554418

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI