Ijọba Kwara gb'eto ipatẹ ọja akọkọ iru ẹ kalẹ f'awọn ọdọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 8, 2021

Ijọba Kwara gb'eto ipatẹ ọja akọkọ iru ẹ kalẹ f'awọn ọdọIjọba ipinlẹ Kwara labẹ akoso gomina AbdulRahman AbdulRazaq l'awọn ti bu ọwọ lu eto ipatẹ ọja igbalode silẹ f'awọn ọdọ, k'awọn naa le jẹ anfaani eto ijọba awaarawa.
 
Eto ọlọjọ meji naa la gbọ pe akọkọ iru ẹ ree ninu itan ipinlẹ naa, tori pe ko ṣẹlẹ ri, ti wọn si ni ileeṣẹ amugbalẹgbẹ gomina l'ori ọrọ to ni i ṣe pẹlu awọn ọdọ lo fẹẹ s'agbatẹru eto naa.
 
Gbọngan ijọba ti wọn pe ni Banquet hall ipinlẹ naa lo ti fẹẹ waye l'ọjọ karun-un si ọjọ kẹfa oṣu kẹfa, l'aaarin aago mẹjọ aarọ si marun-un irọlẹ. 
 
A gbọ pe nibi eto yii l'awọn ọdọ yoo ti fi ẹbun ti wọn ni han, yala nipa iṣẹ ọwọ ni tabi nipa imọ ayelujara, t'onikaluku yoo si patẹ ọja wọn f'awọn eeyan lati ba wọn d'owopọ.
 
Eto iforukọ silẹ la gbọ pe o ti bẹrẹ bayii, ti yoo si kasẹ nilẹ l'ọjọ kẹrindonlogun oṣu yii.
 
Lati f'orukọ silẹ, awọn ikanni yii lẹ ti maa f'orukọ silẹ.
 
For Product Exhibition: http://bit.ly/KYFProduct
For Talent Exhibition: http://bit.ly/KYFTalent
For Business Pitch: http://bit.ly/KYFBusinessPitch

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI