Ẹ w'oju awọn ọmọ kekeeke ti wọn fi n ṣ'iṣẹ aṣẹwo l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 9, 2021

Ẹ w'oju awọn ọmọ kekeeke ti wọn fi n ṣ'iṣẹ aṣẹwo l'Ogun


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
 
Ko din ni awọn mejilelogun awọn ọmọ kekeeke ti wọn ti bọ l'ọwọ oko ẹru amunisin n'ipinlẹ Ogun l'ọsẹ ta a ṣẹṣẹ lo tan yii.
 
Ipinlẹ Akwa-Ibom la gbọ pe wọn ti ko awọn ọmọ naa wa s'agbegbe Itele Ọta n'ipinlẹ Ogun, n'ibi ti wọn ti n lo wọn fun iṣẹ aṣẹwo.
 
Gbajugbaja otẹẹli kereje kan ti wọn pe ni KOLAB ni wọn ti n f'awọn ọmọ naa t'ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹwaa si mẹrinla lọ.
 
Iṣẹ ọmọ ọdọ la gbọ pe wọn sọ f'awọn ọmọ naa pe wọn fẹ lọ fi wọn ṣe n'ipinlẹ Ogun, ti wọn yoo si maa gba owo nla fi ranṣẹ s'awọn obi wọn.
 
Ṣe ni wọn l'ọrọ yi pada n'igba ti wọn de ipinlẹ Ogun, to jẹ pe ṣe ni wọn ko wọn lọ si otẹẹli mo-sa-fun-ẹ-to naa, n'ibi ti wọn ti wọn mọ lati maa fi wọn ṣ'iṣẹ aṣẹwo.
 
AWIKONKO gbọ pe awọn kan ni wọn kofiri awọn ọmọ naa, ti wọn si lọ ọ fi to awọn ọlọpaa l'eti.
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to f'iroyin naa to wa l'eti jẹ ko ye wa pe ọjọ nnkan bi aago mẹjọ alẹ ọjọ Ẹti-Furaidee ni aṣiri wọn tu, ti wọn si ti ko awọn ọmọ naa lọ ọ tọju.
 
Wọn ni bi wọn ṣe ko awọn ọmọ naa de ni wọn ti gba foonu ọwọ wọn lati ma jẹ ki wọn ri awọn obi wọn tabi mọlẹbi wọn ba s'ọrọ lati tu aṣiri iṣẹ ti wọn n fi wọn ṣe.
 
Bakan naa ni ọwọ tun ti tẹ Isaac Ọgbaji, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to ni otẹẹli ti wọn ti n f'awọn ọmọ naa ṣiṣẹ aṣẹwo yii.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wa a p'aṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹ siwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI