O tan! Donald Duke pada si PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 26, 2021

O tan! Donald Duke pada si PDP


Alaga f'idihẹ f'ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Cross River State, Effiok Cobham ti sọ lonii Wẹsidee wi pe gomina tẹlẹri n'ipinlẹ naa, Donald Duke ti pada s'inu ẹgbẹ oṣelu naa.
 
Ilu Calabar bu Cobham ti sọrọ yii l'asiko to n b'awọn akọroyin s'ọrọ, to si ni idunnu nla lo ṣubu lu ayọ awọn.
 
N'igba ti wọn n beere lọwọ ẹ lati f'idi awuyewuye to n lọ kaakiri igboro nipa wi pe Duke ti pada s'inu ẹgbẹ oṣelu naa, o ni "Bẹẹni, koda, o tun ti f'orukọ silẹ."

L'ọdun 2019 nin Duke kuro ninu ẹgbẹ naa lọ sinu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party n'ibi to ti jade du ipo Aarẹ orilẹ-ede yii, ṣugbọn to padanu.
 
Ogunjọ oṣu yii ni GOmina ipinlẹ naa, Ben Ayade f'ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ sinu ẹgbẹ APC.

Aarin ọdun 1999 si ọdun 2007 ni Duke fi jẹ gomina ipinlẹ Cross River.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI