A kò kábàámọ̀ wí pé a fa AbdulRazaq kalẹ̀ láti ṣe Gómìnà Kwara - APC - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 28, 2021

A kò kábàámọ̀ wí pé a fa AbdulRazaq kalẹ̀ láti ṣe Gómìnà Kwara - APC


Ẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti sọ ọ gbangba wi pe awọn ko kábàámọ̀ kankan wi pe AbdulRahman AbdulRazaq lawọn fa kalẹ gẹgẹ bi oludije sipo gomina ipinlẹ naa lọdun meji sẹyin.

Wọn sọ pe àwọn akanṣe iṣẹ manigbagbe ti AbdulRazaq ti ṣe láàárín ọdún méjì to de ori aga aleefa kọja awọn nnkan teeyan le f'ọwọ bo, to si lo o kọja idagbasoke tàwọn ìṣàkóso to koja fi aimọye ọdún ṣe.

Alaga ẹgbẹ naa, Alaaji Abdullahi Samari lo sọrọ yii nibi ipade ita gbangba ti ẹgbẹ naa ṣe agbatẹru rẹ ni ana ti i ṣe Tọsidee, ìyẹn Town Hall Meeting to waye niluu Ilọrin, ipinlẹ naa.

Níbẹ̀ lo ti láwọn ki Gómìnà AbdulRazaq ku oriire ayẹyẹ ọdún keji to de ori ipo naa.

O ni lai fi ti eto ọrọ aje ti ko lọ deede ṣe, sibẹ Gómìnà AbdulRazaq ṣi n gbiyanju lati ri i pe ìdàgbàsókè alailẹgbẹ n ṣẹlẹ kaakiri agbegbe ati igberiko ipinlẹ naa.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI