Ọga ileeṣẹ InksNation dero atimọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 30, 2021

Ọga ileeṣẹ InksNation dero atimọle


Ọmọtade-Sparks Amos Sewanu ti wọn ni gbajugbaja gbajuẹ ni lo ti ha sọwọ awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n gbogun ti iwa jibiti lorilẹ-ede yii, Economic and Financial Crimes Comission.
 
Owo ti ko din ni miliọnu mejilelọgbọn naira ni wọn lo o lu jibiti rẹ, ti wọn si ti n wa a tipẹ.
 
Oludasilẹ ileeṣẹ sogundogoji kan ti wọn pe ni Inks Nation Ponzi Scheme ni wọn pe Sewanu, ọmọ ilẹ Badagry nipinlẹ Eko.

AWIKONKO gbọ pe ileeṣẹ naa lo fi n lu awọn eeyan ni jibiti owo, o si tun n fi ayederu kaadi kan ti wọn fi n gba owo lẹnu ọrọ ni banki, iyẹn ATM ti wọn pe ni PIN CARD fi tan awọn eeyan jẹ.
 
Yatọ si eyi, owo kan ti wọn lawọn eeyan ko gbọ ri ni wọn sọ pe Sewanu loun n na fawọn eeyan lori ayelujara, owo yii naa ni wọn sọ pe awọn eeyan fi n ra ọja lọwọ ara wọn lati lu jibiti.
 
Oṣu kọkanla ọdun to kọja la gbọ pe ileeṣẹ EFCC ti gbe fọto rẹ sita wi pe awọn n wa a ko to bẹrẹ si i sa kaakiri. Ipinlẹ Ṣokoto lọhun lọwọ ti pada tẹ ẹ lỌjọbọ Tọsidee to kọja yii.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI