Ìmọ́tótó: Ẹlẹṣẹ ki yóò lọ láì jìyà - Kọmiṣanna ètò àyíká ni Kwara ṣe ìkìlọ nla fawọn aráàlú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, May 28, 2021

Ìmọ́tótó: Ẹlẹṣẹ ki yóò lọ láì jìyà - Kọmiṣanna ètò àyíká ni Kwara ṣe ìkìlọ nla fawọn aráàlú


Kọmiṣanna fun ọrọ eto ayika nipinlẹ Kwara, Arabinrin Banigbe Rẹmilẹkun Oluwatobi ti sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ awọn agbofinro ba tẹ nipa sisọ idọti kaakiri popona yoo foju winna ofin ijọba.

O ni ìmọ́tótó bori aarun mọlẹ bi ọyẹ ṣe bori oru, bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ilera ri, to si ni fun idi eyi lati le je kawọn araalu.

Banigbe sọrọ yii lakooko to n ṣe abẹwo si ọja Ipata nijọba ibilẹ Ilọrin East lati mọ bi awọn ara ọja naa ṣe n lo ile idalẹsi Roro si.

Lara àwọn to wa níbi abẹwo naa ni alakooso Kwara State Environmental Protection Agency (KWEPA), Alaaji Saad Ayuba Dan Musa ati ikọ akọwọrin wọn.

Nibẹ lo ti sọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ wi pe o da ilẹ sita lai lo awọn idalẹsi Roro naa yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI