Gbajugbaja olukọ ile ẹkọ gbogboniṣe ti Moshood Abiola to wa ni Ojere nilu Abẹokuta, Olufẹmi Ọrunsọla, ẹni t'ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ sí Awe lo tun ti ṣe bẹbẹ bayii.
Orin aladidun kan to pe ni 'Ma J'an L'Aawẹ' lo ti gbe jade fún igbadun awọn araalu, pàápàá lasiko Aawẹ Ramadaani to n lọ lọwọ yii.
Odu ti kì í ṣ'aimo f'oloko ni Awe ninu ka gbe ọpọlọ orin kalẹ.
Ninu orin 'Ma J'an L'Aawẹ' to da bi awada lo ti n ṣe ìkìlọ f'awọn obinrin láti máa mọ bi wọn yóò ṣe máa múra.
Kì í ṣe ahesọ tabi asọdun wí pé aṣọ iwọkuwọ ti gba igboro lasiko yii, pàápàá láàárín àwọn obìnrin.
Eyi ló mu kí Awe ronú lati gba awọn obinrin lamọran nipa iru aṣọ ti wọn yóò máa wọ lasiko ti Aawẹ Ramadaani n lọ lọwọ, lati ma ṣe ṣí àwọn ọkunrin lọnà Ọlọhun.
Ẹ jẹ igbadun orin naa:
No comments:
Post a Comment