A ṣetan lati tubọ maa ro awọn ọjẹwẹwẹ lagbara lẹka ere idaraya - Ajọ FOLIAGE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 20, 2021

A ṣetan lati tubọ maa ro awọn ọjẹwẹwẹ lagbara lẹka ere idaraya - Ajọ FOLIAGE


Awọn alakoso ajọ alaanu kan ti wọn pe ni Fold for Liberal Age Charity Initiative, FOLIAGE ti sọ pe awọn ti ṣetan lati tubọ maa tẹsiwaju nipa riro awọn ọdọ ati ogowẹẹrẹ lagbara, paapaa lẹka eto ere idaraya kaakiri orileede Naijiria.

Laipẹ yii ni awọn alakoso ajọ naa sọrọ yii niluu Akurẹ, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ondo lẹyin idije ifigagbaga kan ti wọn ṣagbatẹru ẹ, nibi tawọn ọjẹwẹwẹ atawọn ọdọ ti kopa.

Nigba to n sọrọ naa, alakoso eto naa, Arabinrin Ọmọwe (Arabinrin) Tolu Fadipẹ, ẹni ti igbakeji rẹ, Ọmọọba Adefẹmi Adewumi ṣoju fun sọ pe awọn ipẹẹrẹ (teens) ni afojusun wọn wa fun lati ri i pe wọn ri ere idaraya gẹgẹ bi anfaani lati fi ro ara wọn lagbara.

O ni awọn ere idaraya bi i bọọlu alafẹsẹgba, ẹyin ori tabili, iwe odo igbalode (swimming) ati bẹẹbẹẹlọ lawọn ni ninu agbekalẹ wọn lati fi ro awọn ọjẹwẹwẹ naa lagbara.

Nigba to n fi idunnu rẹ han si ti idije ti wọn ṣẹṣẹ pari laipẹ yii, alaga ati oludasilẹ ajọ FOLIAGE, Ọgbẹni Fẹmi Ayejusunle dupẹ gidigidi lọwọ awọn akopa, oluranwọ, to fi mọ awọn alẹnulọrọ ti wọn dide si aṣeyọri naa.

O ni erongba wọn ni lati gbe ẹbun awọn ogo wẹẹrẹ dide nipa ere idaraya, gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe lawọn ilẹ okeere ti wọn ti ni idagbasoke, paapaa lẹka eto ere idaraya loriṣiriṣi.

Bakan naa, alakoso eto ere idaraya nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Henry Babatunde, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Mista White, gba awọn ajọ aladani kaakiri agbaye, paapaa nipinlẹ naa lamọran lati dide ran awọn ogo wẹẹrẹ lọwọ lẹka ere idaraya, paapaa ti ẹsin ori tabili ti a mọ si Tennis.

O lawọn bi i iyawo gomina ipinlẹ naa, Arabinrin Betty Anyanwu Akeredolu ati ajọ FOLIAGE ni wọn ṣi n ṣe akitiyan lati ri i pe ere idaraya ko parẹ nipinlẹ Ondo.

Lara awọn to tun wa nibi eto yii ni akọnimọngba ẹṣin ori tabili nipinlẹ naa, Mayọwa Joshua; Ọgbẹni Oluwafẹmi Adelẹyẹ to jẹ akọwe ẹgbẹ naa, atawọn mi in.







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI