Iṣẹ ajagungbalẹ lawọn eleyi n ṣe jẹun nipinlẹ Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, June 20, 2021

Iṣẹ ajagungbalẹ lawọn eleyi n ṣe jẹun nipinlẹ Ogun


Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
 
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn mẹta kan ti wọn ko niṣẹ mi in ju iṣẹ ajagungbalẹ lọ nipinlẹ Ogun.
 
Ọjọ Ẹti, Furaide lọwọ tẹ awọn mẹtẹẹta ti wọn pe orukọ wọn ni Wasiu Adenuga, Michael John ati Mọruf Alaba lagbegbe Ituṣokun, Odogbolu, ipinlẹ naa.
 
AWIKONKO gbọ pe
obinrin kan, Kẹmi Olukọya lo lọ fi ẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, ẹkun Odogbolu wi pe awọn ajagungbalẹ wa n di oun lọwọ iṣẹ ile oun toun n kọ sagbegbe Ituṣokun, ati pe wọn tun lu gbogbo awọn ti wọn n ba oun ṣiṣẹ lalubami.
 
Kẹmi sọ fawọn ọlọpaa wi pe mẹjọ lawọn ajagungbalẹ naa ti wọn wa kọlu wọn pẹlu awọn nnkan ija oloro bi i ibọn, ada, igo atawọn mi in, eyi ti wọn fi dẹru ba wọn.
 
O tẹsiwaju pe ibi ti wọn ti n le wọn ni wọn tun ti ja baagi oun gba, ti wọn si ko ẹgbẹrun marun-un naira toun ni nibẹ, pẹlu foonu toun ra ni ẹgbẹrun lọna ogoji naira salọ.
 
Ẹsun yii lo bi ọga ọlọpaa ẹkun naa, Adeniyi Awokunle ninu, to fi lewaju awọn ọlọpaa abẹ ẹ lọ sibẹ lati lọ koju wọn.
 
Wọn ni bawọn ajagungbalẹ yii ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn ti juba ehoro, ti wọn si na papa bora, ki ọwọ ma ba a tẹ wọn. Loju ẹsẹ ni wọn lawọn ọlọpaa naa ti le wọn, ti ọwọ si tẹ ọkan lara wọn ti wọn pe ni Wasiu Adenuga.
 
A gbọ pe awọn ọlọpaa yii ko duro rara lori ẹnikan ṣoṣo ti wọn mu naa, ti wọn si le awọn yooku lọ, ṣugbọn to jẹ pe meji pere lọwọ tun pada tẹ, tawọn yooku si raaye salọ.
 
AWIKONKO gbọ pe ọkada Bajaj mẹta ti wọn gbe dani lọọ jagun lawọn ọlọpaa tun ti gbẹsẹ le bayii.
 
Olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta lawọn mẹtẹẹta wa bayii, nibi ti wọn ti n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iṣẹ iwadii wọn.
 

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun,
Edward Awolowo Ajogun, ti wa a paṣẹ pe ki wọn lọ foju wọn ba ile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari, ati pe ki wọn ri i daju pe ọwọ tẹ awọn yooku ti wọn na papa bora naa.

1 comment:

  1. They have turn to terrorists in Odogbolu, I pray their case reach court, because am sure their God father will look for ways to release them. Odogbolu must be free from violent again.

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI